Nwọn si kigbe pe Oluwa, nwọn si wipe, Awa ti dẹsẹ̀, nitoripe awa ti kọ̀ Oluwa silẹ, awa si ti nsin Baalimu ati Aṣtaroti: ṣugbọn nisisiyi, gba wa lọwọ́ awọn ọta wa, awa o si sìn ọ.