Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Sam 10:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. SAMUELI si mu igo ororo, o si tu u si i li ori, o si fi ẹnu kò o li ẹnu, o si wipe, Kò ṣepe nitoriti Oluwa ti fi ororo yàn ọ li olori ini rẹ̀?

2. Nigbati iwọ ba lọ kuro lọdọ mi loni, iwọ o ri ọkunrin meji li ẹba iboji Rakeli li agbegbe Benjamini, ni Selsa; nwọn o si wi fun ọ pe, Nwọn ti ri awọn kẹtẹkẹtẹ ti iwọ ti jade lọ iwá: si wõ, baba rẹ ti fi ọran ti kẹtẹkẹtẹ silẹ, o si kọ ominu nitori rẹ wipe, Kili emi o ṣe niti ọmọ mi?

3. Iwọ o si kọja lati ibẹ lọ, iwọ o si de pẹtẹlẹ Tabori, nibẹ li ọkunrin mẹta ti nlọ sọdọ Ọlọrun ni Beteli yio pade rẹ, ọkan yio mu, ọmọ ewurẹ mẹta lọwọ, ekeji yio mu iṣù akara mẹta, ati ẹkẹta yio mu igo ọti-waini.

4. Nwọn o si ki ọ, nwọn o si fi iṣù akara meji fun ọ; iwọ o si gbà a lọwọ wọn.

5. Lẹhin eyini iwọ o wá si oke Ọlọrun, nibiti ẹgbẹ ogun awọn Filistini wà; yio si ṣe, nigbati iwọ ba de ilu na, iwọ o si pade ẹgbẹ woli ti yio ma sọkalẹ lati ibi giga nì wá; nwọn o si ni psalteri, ati tabreti, ati fère, ati harpu niwaju wọn, nwọn o si ma sọtẹlẹ.

6. Ẹmi Oluwa yio si bà le ọ, iwọ o si ma ba wọn sọtẹlẹ, iwọ o si di ẹlomiran.

7. Yio si ri bẹ̃, nigbati àmi wọnyi ba de si ọ, ṣe fun ara rẹ ohun gbogbo ti ọwọ́ rẹ ba ri lati ṣe, nitoriti Ọlọrun wà pẹlu rẹ.

8. Iwọ o si ṣaju mi sọkalẹ lọ si Gilgali, si kiye si i, emi o sọkalẹ tọ ọ wá, lati rubọ sisun, ati lati ru ẹbọ irẹpọ̀: ni ijọ meje ni iwọ o duro, titi emi o fi tọ̀ ọ wá, emi o si fi ohun ti iwọ o ṣe han ọ.

9. O si ri bẹ̃ pe, nigbati o yi ẹhin rẹ̀ pada lati lọ kuro lọdọ Samueli, Ọlọrun si fun u li ọkàn miran: gbogbo àmi wọnni si ṣẹ li ọjọ na.

10. Nigbati nwọn si de ibẹ si oke na, si kiye si i, ẹgbẹ awọn woli pade rẹ̀, Ẹmi Ọlọrun si bà le e, on si sọtẹle larin wọn.

11. O si ṣe, nigbati gbogbo awọn ti o mọ̀ ọ ri pe o nsọtẹlẹ larin awọn woli, awọn enia si nwi fun ara wọn pe, Kili eyi ti o de si ọmọ Kiṣi? Saulu wà ninu awọn wolĩ pẹlu?

12. Ẹnikan lati ibẹ na wá si dahùn, o si wipe, ṣugbọn tani baba wọn? Bẹ̃li o si wà li owe, Saulu wà ninu awọn wolĩ pẹlu?

Ka pipe ipin 1. Sam 10