Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 5:21-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Nwọn si kó ẹran ọ̀sin wọn lọ; ibakasiẹ ẹgbãmẹ̃dọgbọ̀n ati àgutan ọkẹ mejila o le ẹgbãrun, ati kẹtẹkẹtẹ ẹgbã, ati enia ọkẹ marun.

22. Nitori ọ̀pọlọpọ li o ṣubu ti a pa, nitori lati ọdọ Ọlọrun li ogun na. Nwọn si joko ni ipò wọn titi di igbà ikolọ si ìgbekun.

23. Awọn ọmọkunrin àbọ ẹ̀ya Manasse joko ni ilẹ na: nwọn bi si i lati Baṣani titi de Baal-hermoni, ati Seniri, ati titi de òke Hermoni.

24. Wọnyi si li awọn olori ile awọn baba wọn, Eferi, ati Iṣi, ati Elieli, ati Asrieli, ati Jeremiah, ati Hodafiah, ati Jahdieli, awọn alagbara akọni ọkunrin, ọkunrin olokiki, ati olori ile awọn baba wọn.

25. Nwọn si ṣẹ̀ si Ọlọrun awọn baba wọn, nwọn si ṣe àgbere tọ awọn ọlọrun enia ilẹ na lẹhin, ti Ọlọrun ti parun ni iwaju wọn.

26. Ọlọrun Israeli rú ẹmi Pulu ọba Assiria soke, ati ẹmi Tiglat-pilneseri ọba Assiria, on si kó wọn lọ, ani awọn ọmọ Rubeni ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, o si kó wọn wá si Hala, ati Habori, ati Hara, ati si odò Goṣani, titi di oni yi.

Ka pipe ipin 1. Kro 5