Ọlọrun Israeli rú ẹmi Pulu ọba Assiria soke, ati ẹmi Tiglat-pilneseri ọba Assiria, on si kó wọn lọ, ani awọn ọmọ Rubeni ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, o si kó wọn wá si Hala, ati Habori, ati Hara, ati si odò Goṣani, titi di oni yi.