Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 28:8-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Njẹ nisisiyi li oju gbogbo Israeli ijọ enia Oluwa, ati li eti Ọlọrun wa, ẹ ma pamọ́ ki ẹ si ma ṣafẹri gbogbo ofin Oluwa Ọlọrun nyin: ki ẹ le ni ilẹ rere yi, ki ẹ si le fi i silẹ li ogún fun awọn ọmọ nyin lẹhin nyin lailai.

9. Ati iwọ, Solomoni ọmọ mi, mọ̀ Ọlọrun baba rẹ, ki o si fi aiya pipé ati fifẹ ọkàn sìn i: nitori Oluwa a ma wá gbogbo aiya, o si mọ̀ gbogbo ete ironu: bi iwọ ba ṣafẹri rẹ̀, iwọ o ri i; ṣugbọn bi iwọ ba kọ̀ ọ silẹ on o ta ọ nù titi lai.

10. Wò o nisisiyi: nitori Oluwa ti yàn ọ lati kọ́ ile kan fun ibi mimọ́, mura le, ki iwọ si ṣe e.

11. Nigbana ni Dafidi fi apẹrẹ fun Solomoni ọmọ rẹ̀ ti iloro, ati ti ile rẹ̀, ati ti ibi iṣura rẹ̀, ati ti iyara-òke rẹ̀, ati ti gbangan inu rẹ̀ ati ti ibi ibujoko ãnu,

Ka pipe ipin 1. Kro 28