Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 28:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. DAFIDI si kó gbogbo ijoye Israeli jọ, awọn ijoye ẹ̀ya, ati awọn ijoye awọn ẹgbẹ ti nṣe iranṣẹ fun ọba, ati awọn ijoye lori ẹgbẹgbẹrun, ati awọn ijoye lori ọrọrun, ati awọn ijoye lori gbogbo ọrọ̀ ati ini ọba, ati ti awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu awọn balogun, ati pẹlu awọn alagbara enia, ati gbogbo akọni enia si Jerusalemu.

2. Nigbana ni Dafidi ọba dide duro li ẹsẹ rẹ̀, o si wipe, Ẹ gbọ́ ti emi, ẹnyin arakunrin mi ati enia mi: emi fẹ li ọkàn mi lati kọ́ ile isimi kan fun apoti ẹri majẹmu Oluwa, ati fun itisẹ Ọlọrun wa, mo si ti mura tan fun kikọ́le na:

3. Ṣugbọn Ọlọrun sọ fun mi pe, Iwọ kò gbọdọ kọ́ ile fun orukọ mi, nitori ologun ni iwọ, o si ti ta ẹ̀jẹ silẹ.

4. Oluwa Ọlọrun Israeli si yàn mi lati inu gbogbo ile baba mi lati jẹ ọba lori Israeli lailai: nitori ti o ti yàn Juda li olori; ati ninu ile Juda, ile baba mi: ati larin awọn ọmọ baba mi o fẹ mi lati jẹ ọba gbogbo Israeli.

5. Ati ninu gbogbo ọmọ mi ọkunrin (nitori ti Oluwa ti fun mi li ọmọkunrin pupọ), o ti yàn Solomoni ọmọ mi lati joko lori itẹ ijọba Oluwa lori Israeli.

6. On si wi fun mi pe, Solomoni ọmọ rẹ, on yio kọ́ ile mi ati agbala mi: nitori emi ti yàn a li ọmọ mi, emi o si jẹ baba fun u.

7. Pẹlupẹlu emi o fi idi ijọba rẹ̀ mulẹ lailai, bi o ba murale lati ṣe ofin mi ati idajọ mi bi li oni yi.

8. Njẹ nisisiyi li oju gbogbo Israeli ijọ enia Oluwa, ati li eti Ọlọrun wa, ẹ ma pamọ́ ki ẹ si ma ṣafẹri gbogbo ofin Oluwa Ọlọrun nyin: ki ẹ le ni ilẹ rere yi, ki ẹ si le fi i silẹ li ogún fun awọn ọmọ nyin lẹhin nyin lailai.

9. Ati iwọ, Solomoni ọmọ mi, mọ̀ Ọlọrun baba rẹ, ki o si fi aiya pipé ati fifẹ ọkàn sìn i: nitori Oluwa a ma wá gbogbo aiya, o si mọ̀ gbogbo ete ironu: bi iwọ ba ṣafẹri rẹ̀, iwọ o ri i; ṣugbọn bi iwọ ba kọ̀ ọ silẹ on o ta ọ nù titi lai.

10. Wò o nisisiyi: nitori Oluwa ti yàn ọ lati kọ́ ile kan fun ibi mimọ́, mura le, ki iwọ si ṣe e.

Ka pipe ipin 1. Kro 28