Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. Kro 10:7-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Nigbati gbogbo awọn ọkunrin Israeli ti o wà ni pẹtẹlẹ ri pe nwọn sá, ati pe Saulu ati awọn ọmọ rẹ̀ kú, nwọn fi ilu wọn silẹ, nwọn si sá: awọn ara Filistia si wá; nwọn si joko ninu wọn.

8. O si ṣe ni ijọ keji, nigbati awọn ara Filistia de lati wá bọ́ awọn okú li aṣọ, nwọn si ri Saulu pẹlu, ati awọn ọmọ rẹ̀ pe; nwọn ṣubu li òke Gilboa.

9. Nwọn si bọ́ ọ li aṣọ, nwọn si gbé ori rẹ̀ ati ihamọra rẹ̀, nwọn si ranṣẹ si awọn ara Filistia yika, lati mu ihin lọ irò fun awọn ere wọn, ati fun awọn enia.

10. Nwọn si fi ihamọra rẹ̀ sinu ile oriṣa wọn, nwọn si kan agbari rẹ̀ mọ ile Dagoni.

11. Nigbati gbogbo Jabeṣ-gileadi gbọ́ gbogbo eyi ti awọn ara Filistia ti ṣe si Saulu,

12. Nwọn dide, gbogbo awọn ọkunrin ogun, nwọn si gbé okú Saulu lọ, ati okú awọn ọmọ rẹ̀, nwọn wá si Jabeṣi, nwọn si sìn egungun wọn labẹ igi oaku ni Jabeṣi, nwọn si gbawẹ ni ijọ meje.

13. Bẹ̃ni Saulu kú ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀ ti o da si Oluwa, nitori ọ̀rọ Oluwa, ti on kò kiyesi, ati pẹlu nitori o lọ bère ọ̀ràn lọwọ abokusọrọ, lati ṣe ibere.

14. Kò si bère lọwọ Oluwa; nitorina li o ṣe pa a, o si yi ijọba na pada sọdọ Dafidi ọmọ Jesse.

Ka pipe ipin 1. Kro 10