Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 8:7-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Nitori awọn kerubu nà iyẹ wọn mejeji si ibi apoti-ẹri, awọn kerubu na si bò apọti-ẹri ati awọn ọpá rẹ̀ lati oke wá.

8. Nwọn si fa awọn ọpá na jade tobẹ̃ ti a nfi ri ori awọn ọpá na lati ibi mimọ́ niwaju ibi-idahùn, a kò si ri wọn lode: nibẹ ni awọn si wà titi di oni yi.

9. Kò si nkankan ninu apoti-ẹri bikoṣe tabili okuta meji, ti Mose ti fi si ibẹ ni Horebu nigbati Oluwa ba awọn ọmọ Israeli dá majẹmu, nigbati nwọn ti ilẹ Egipti jade.

10. O si ṣe, nigbati awọn alufa jade lati ibi mimọ́ wá, awọsanma si kún ile Oluwa.

11. Awọn alufa kò si le duro ṣiṣẹ nitori awọsanma na: nitori ogo Oluwa kún ile Oluwa.

12. Nigbana ni Solomoni sọ pe: Oluwa ti wi pe, on o mã gbe inu okùnkun biribiri.

13. Nitõtọ emi ti kọ́ ile kan fun ọ lati mã gbe inu rẹ̀, ibukojo kan fun ọ lati mã gbe inu rẹ̀ titi lai.

14. Ọba si yi oju rẹ̀, o si fi ibukún fun gbogbo ijọ enia Israeli: gbogbo ijọ enia Israeli si dide duro;

15. O si wipe, Ibukún ni fun Oluwa, Ọlọrun Israeli, ti o fi ẹnu rẹ̀ sọ̀rọ fun Dafidi, baba mi, ti o si fi ọwọ́ rẹ̀ mu u ṣẹ, wipe,

16. Lati ọjọ ti emi ti mu Israeli, awọn enia mi jade kuro ni Egipti, emi kò yàn ilu kan ninu gbogbo ẹyà Israeli lati kọ́ ile kan, ki orukọ mi ki o le mã gbe inu rẹ̀: ṣugbọn emi yàn Dafidi ṣe olori Israeli, awọn enia mi.

17. O si wà li ọkàn Dafidi, baba mi, lati kọ́ ile kan fun orukọ Oluwa, Ọlọrun Israeli.

18. Oluwa si wi fun Dafidi baba mi pe, Bi o tijẹpe o wà li ọkàn rẹ lati kọ́ ile kan fun orukọ mi, iwọ ṣe rere ti o fi wà li ọkàn rẹ.

19. Ṣibẹ̀ iwọ kì yio kọ́ ile na, ṣugbọn ọmọ rẹ ti yio ti inu rẹ jade, on ni yio kọ́ ile na fun orukọ mi.

20. Oluwa si mu ọ̀rọ rẹ̀ ṣẹ ti o ti sọ, emi si dide ni ipò Dafidi, baba mi, mo si joko lori itẹ́ Israeli, gẹgẹ bi Oluwa ti sọ, emi si kọ́ ile kan fun orukọ Oluwa, Ọlọrun Israeli.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 8