Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 7:23-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. O si ṣe agbada nla didà igbọnwọ mẹwa lati eti kan de ekeji: o ṣe birikiti, giga rẹ̀ si jẹ igbọnwọ marun: okùn ọgbọ̀n igbọnwọ li o si yi i kakiri.

24. Ati nisalẹ eti rẹ̀ yikakiri kóko wà yi i ka, mẹwa ninu igbọnwọ kan, o yi agbada nla na kakiri: a dà kóko na ni ẹsẹ meji, nigbati a dà a.

25. O duro lori malu mejila, mẹta nwo iha ariwa, mẹta si nwo iwọ-õrun, mẹ̃ta si nwo gusu, mẹta si nwo ila-õrun; agbada nla na si joko lori wọn, gbogbo apa ẹhin wọn si mbẹ ninu.

26. O si nipọn to ibú atẹlẹwọ, a si fi itanna lili ṣiṣẹ eti rẹ̀ gẹgẹ bi eti ago, o si gbà ẹgbã iwọ̀n Bati.

27. O si ṣe ijoko idẹ mẹwa; igbọnwọ mẹrin ni gigùn ijoko kọkan, igbọnwọ mẹrin si ni ibú rẹ̀, ati igbọnwọ mẹta ni giga rẹ̀.

28. Iṣẹ awọn ijoko na ri bayi: nwọn ni alafo ọ̀na arin, alafo ọ̀na arin na si wà lagbedemeji ipade eti.

29. Ati lara alafo ọ̀na arin ti mbẹ lagbedemeji ni aworan kiniun, malu, ati awọn kerubu wà; ati lori ipade eti, ijoko kan wà loke: ati labẹ awọn kiniun, ati malu ni iṣẹ ọṣọ́ wà.

30. Olukuluku ijoko li o ni ayika kẹkẹ́ idẹ mẹrin, ati ọpa kẹkẹ́ idẹ: igun mẹrẹrin rẹ̀ li o ni ifẹsẹtẹ labẹ; labẹ agbada na ni ifẹsẹtẹ didà wà, ni iha gbogbo iṣẹ ọṣọ́ na.

31. Ẹnu rẹ̀ ninu ipari na ati loke jẹ igbọnwọ kan: ṣugbọn ẹnu rẹ̀ yika gẹgẹ bi iṣẹ ijoko na, si jẹ igbọnwọ kan on àbọ: ati li ẹnu rẹ̀ ni ohun ọnà gbigbẹ́ wà pẹlu alafo ọ̀na arin wọn, nwọn si dọgba ni igun mẹrẹrin, nwọn kò yika.

32. Ati nisalẹ alafo ọ̀na arin, ayika-kẹkẹ́ mẹrin li o wà: a si so ọpa ayika-kẹkẹ́ na mọ ijoko na; giga ayika-kẹkẹ́ kan si jẹ igbọnwọ kan pẹlu àbọ.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 7