Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 4:18-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Ṣimei, ọmọ Ela, ni Benjamini.

19. Geberi, ọmọ Uri wà ni ilẹ Gileadi ni ilẹ Sihoni, ọba awọn ara Amori, ati Ogu, ọba Baṣani: ijoye kan li o si wà ni ilẹ na.

20. Juda ati Israeli pọ̀ gẹgẹ bi iyanrin ti mbẹ li eti okun ni ọ̀pọlọpọ, nwọn njẹ, nwọn si nmu, nwọn si nṣe ariya.

21. Solomoni si jọba lori gbogbo awọn ọba lati odò titi de ilẹ awọn ara Filistia, ati titi de eti ilẹ Egipti: nwọn nmu ọrẹ wá, nwọn si nsìn Solomoni ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀.

22. Onjẹ Solomoni fun ijọ kan jasi ọgbọ̀n iyẹ̀fun kikunna ati ọgọta oṣuwọn iyẹ̀fun iru miran.

23. Malu mẹwa ti o sanra, ati ogún malu lati inu papa wá, ati ọgọrun agutan, laika agbọ̀nrin, ati egbin, ati ogbúgbu, ati ẹiyẹ ti o sanra.

24. Nitori on li o ṣe alaṣẹ lori gbogbo agbègbe ni iha ihin odò, lati Tifsa titi de Gasa, lori gbogbo awọn ọba ni iha ihin odò: o si ni alafia ni iha gbogbo yi i kakiri.

25. Juda ati Israeli ngbe li alafia, olukuluku labẹ àjara rẹ̀ ati labẹ igi ọpọtọ́ rẹ̀, lati Dani titi de Beerṣeba, ni gbogbo ọjọ Solomoni.

26. Solomoni si ni ẹgbãji ile-ẹṣin fun kẹkẹ́ rẹ̀, ati ẹgbãfa ẹlẹṣin.

27. Awọn ijoye na si pesè onjẹ fun Solomoni ọba, ati fun gbogbo awọn ti o wá sibi tabili Solomoni ọba, olukuluku li oṣu tirẹ̀: nwọn kò fẹ nkankan kù.

28. Ọkà barle pẹlu, ati koriko fun ẹṣin ati fun ẹṣin sisare ni nwọn mu wá sibiti o gbe wà, olukuluku gẹgẹ bi ilana tirẹ̀.

29. Ọlọrun si fun Solomoni li ọgbọ́n ati oye li ọ̀pọlọpọ, ati oye gbigboro, gẹgẹ bi iyanrin ti o wà leti okun.

30. Ọgbọ́n Solomoni si bori ọgbọ́n gbogbo awọn ọmọ ila-õrun, ati gbogbo ọgbọ́n Egipti.

31. On si gbọ́n jù gbogbo enia; jù Etani, ara Esra, ati Hemani, ati Kalkoli, ati Dara, awọn ọmọ Maholi: okiki rẹ̀ si kàn ni gbogbo orilẹ-ède yíka.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 4