23. Ọba si wipe, Ọkan wipe, eyi li ọmọ mi ti o wà lãye, ati okú li ọmọ rẹ; ekeji si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn eyi okú li ọmọ rẹ, eyi alãye li ọmọ mi.
24. Ọba si wipe, Ẹ mu idà fun mi wá. Nwọn si mu idà wá siwaju ọba.
25. Ọba si wipe, Ẹ là eyi alãye ọmọ si meji, ki ẹ si mu idaji fun ọkan ati idaji fun ekeji.
26. Obinrin ti eyi alãye ọmọ iṣe tirẹ̀ si wi fun ọba, nitori ti inu rẹ̀ yọ́ si ọmọ rẹ̀, o si wipe, Jọwọ, oluwa mi, ẹ fun u ni eyi alãye ọmọ, ki a máṣe pa a rara. Ṣugbọn eyi ekeji si wipe, kì yio jẹ temi tabi tirẹ, ẹ là a.
27. Ọba si dahùn o si wipe, ẹ fi alãye ọmọ fun u, ki ẹ má si ṣe pa a: on ni iya rẹ̀.
28. Gbogbo Israeli si gbọ́ idajọ ti ọba ṣe; nwọn si bẹ̀ru niwaju ọba: nitoriti nwọn ri i pe, ọgbọ́n Ọlọrun wà ninu rẹ̀, lati ṣe idajọ.