Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 3:15-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Solomoni si jí; si wò o, alá ni. On si wá si Jerusalemu, o si duro niwaju apoti majẹmu Oluwa, o si rubọ ọrẹ sisun, o si ru ẹbọ-alafia, o si se àse fun gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀.

16. Nigbana ni obinrin meji, ti iṣe àgbere, wá sọdọ ọba nwọn si duro niwaju rẹ̀.

17. Ọkan ninu wọn si wipe, Jọwọ, oluwa mi, emi ati obinrin yi ngbe ile kan; emi si bi ọmọ ni ile pẹlu rẹ̀.

18. O si ṣe ni ọjọ kẹta lẹhin igbati mo bimọ tan, obinrin yi si bimọ pẹlu: awa si jumọ ngbé pọ: kò si si alejo pẹlu wa ni ile bikoṣe awa mejeji ni ile.

19. Ọmọ obinrin yi si kú li oru; nitoriti o sun le e.

20. O si dide li ọ̀ganjọ, o si gbe ọmọ mi lati iha mi, nigbati iranṣẹ-birin rẹ sun, o si tẹ́ ẹ si aiya rẹ̀, o si tẹ́ okú ọmọ tirẹ̀ si aiya mi.

21. Mo si dide li owurọ lati fi ọmú fun ọmọ mi, si wò o, o ti kú: ṣugbọn nigbati mo wò o fin li owurọ̀, si wò o, kì iṣe ọmọ mi ti mo bí.

22. Obinrin keji si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn eyi alãye ni ọmọ mi, eyi okú li ọmọ rẹ, eyi si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn eyi okú li ọmọ rẹ, eyi alãye si li ọmọ mi. Bayi ni nwọn nsọ niwaju ọba.

23. Ọba si wipe, Ọkan wipe, eyi li ọmọ mi ti o wà lãye, ati okú li ọmọ rẹ; ekeji si wipe, Bẹ̃kọ; ṣugbọn eyi okú li ọmọ rẹ, eyi alãye li ọmọ mi.

24. Ọba si wipe, Ẹ mu idà fun mi wá. Nwọn si mu idà wá siwaju ọba.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 3