Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 20:7-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Nigbana ni ọba Israeli pè gbogbo awọn àgba ilu, o si wipe, Ẹ fiyèsi i, emi bẹ̀ nyin, ki ẹ si wò bi ọkunrin yi ti nfẹ́ ẹ̀fẹ: nitoriti o ranṣẹ si mi fun awọn aya mi, ati fun awọn ọmọ mi, ati fun fadaka mi, ati fun wura mi, emi kò si fi dù u.

8. Ati gbogbo awọn àgba ati gbogbo awọn enia wi fun u pe, Máṣe fi eti si tirẹ̀, bẹ̃ni ki o máṣe gbà fun u.

9. Nitorina li o sọ fun awọn onṣẹ Benhadadi pe, Wi fun oluwa mi ọba pe, ohun gbogbo ti iwọ ranṣẹ fun, sọdọ iranṣẹ rẹ latetekọṣe li emi o ṣe: ṣugbọn nkan yi li emi kò le ṣe. Awọn onṣẹ na pada lọ, nwọn si tun mu èsi fun u wá.

10. Benhadadi si ranṣẹ si i, o si wipe, Ki awọn oriṣa ki o ṣe bẹ̃ si mi, ati jù bẹ̃ lọ pẹlu bi ẽkuru Samaria yio to fun ikunwọ fun gbogbo enia ti ntẹle mi.

11. Ọba Israeli si dahùn, o si wipe, Wi fun u pe, Má jẹ ki ẹniti nhamọra, ki o halẹ bi ẹniti mbọ́ ọ silẹ,

12. O si ṣe, nigbati Benhadadi gbọ́ ọ̀rọ yi, bi o ti nmuti, on ati awọn ọba ninu agọ, li o sọ fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ tẹ́gun si ilu na.

13. Si kiyesi i, woli kan tọ̀ Ahabu, ọba Israeli wá, wipe, Bayi li Oluwa wi, Iwọ ri gbogbo ọ̀pọlọpọ yi? kiyesi i, emi o fi wọn le ọ lọwọ loni; iwọ o si mọ̀ pe, Emi li Oluwa.

14. Ahabu wipe, Nipa tani? On si wipe, Bayi li Oluwa wi, Nipa awọn ipẹrẹ̀ awọn ijoye igberiko. Nigbana li o wipe, Tani yio wé ogun na? On si dahùn pe: Iwọ.

15. Nigbana li o kà awọn ipẹrẹ̀ awọn ijoye igberiko, nwọn si jẹ igba o le mejilelọgbọn: lẹhin wọn li o si kà gbogbo awọn enia, ani gbogbo awọn ọmọ Israeli jẹ ẹdẹgbarin.

16. Nwọn si jade lọ li ọjọ-kanri. Ṣugbọn Benhadadi mu amupara ninu agọ, on, ati awọn ọba, awọn ọba mejilelọgbọn ti nràn a lọwọ.

17. Awọn ipẹrẹ̀ awọn ijoye igberiko tètekọ jade lọ: Benhadadi si ranṣẹ jade, nwọn si sọ fun u wipe, awọn ọkunrin nti Samaria jade wá.

18. On si wipe, Bi nwọn ba bá ti alafia jade, ẹ mu wọn lãye; tabi bi ti ogun ni nwọn ba bá jade, ẹ mu wọn lãye.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 20