Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 14:8-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Ti mo si fà ijọba ya kuro ni ile Dafidi, mo si fi i fun ọ: sibẹ iwọ kò ri bi Dafidi iranṣẹ mi, ẹniti o pa ofin mi mọ, ti o si tọ̀ mi lẹhin tọkàntọkàn rẹ̀, lati ṣe kiki eyi ti o tọ li oju mi:

9. Ṣugbọn iwọ ti ṣe buburu jù gbogbo awọn ti o ti wà ṣaju rẹ: nitori iwọ ti lọ, iwọ si ti ṣe awọn ọlọrun miran, ati ere didà, lati ru ibinu mi, ti iwọ si ti gbé mi sọ si ẹhin rẹ:

10. Nitorina, kiyesi i, emi o mu ibi wá si ile Jeroboamu, emi o ke gbogbo ọdọmọkunrin kuro lọdọ Jeroboamu, ati ọmọ-ọdọ ati omnira ni Israeli, emi o si mu awọn ti o kù ni ile Jeroboamu kuro, gẹgẹ bi enia ti ikó igbẹ kuro, titi gbogbo rẹ̀ yio fi tan.

11. Ẹni Jeroboamu ti o ba kú ni ilu li awọn ajá yio jẹ: ati ẹniti o ba kú ni igbẹ li awọn ẹiyẹ oju-ọrun yio jẹ: nitori Oluwa ti sọ ọ.

12. Nitorina, iwọ dide, lọ si ile rẹ: nigbati ẹsẹ rẹ ba si wọ̀ ilu, ọmọ na yio kú.

13. Gbogbo Israeli yio si ṣọ̀fọ rẹ̀, nwọn o si sin i; nitori kiki on nikan li ẹniti yio wá si isa-okú ninu ẹniti iṣe ti Jeroboamu, nitori lọdọ rẹ̀ li a ri ohun rere diẹ sipa Oluwa, Ọlọrun Israeli, ni ile Jeroboamu.

14. Oluwa yio si gbé ọba kan dide lori Israeli, ti yio ke ile Jeroboamu kuro li ọjọ na: ṣugbọn kini? ani nisisiyi!

15. Nitoriti Oluwa yio kọlu Israeli bi a ti imì iye ninu omi, yio si fa Israeli tu kuro ni ilẹ rere yi, ti o ti fi fun awọn baba wọn, yio si fọ́n wọn ka kọja odò na, nitoriti nwọn ṣe ere oriṣa wọn, nwọn si nru ibinu Oluwa.

16. Yio si kọ̀ Israeli silẹ nitori ẹ̀ṣẹ Jeroboamu, ẹniti o ṣẹ̀, ti o si mu Israeli dẹṣẹ.

17. Aya Jeroboamu si dide, o si lọ, o si de Tira: nigbati o si wọ̀ iloro ile, ọmọde na si kú;

18. Nwọn si sin i; gbogbo Israeli si sọ̀fọ rẹ̀, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, ti o sọ nipa ọwọ́ iranṣẹ rẹ̀, Ahijah woli.

19. Ati iyokù iṣe Jeroboamu, bi o ti jagun, ati bi o ti jọba, kiyesi i, a kọ wọn sinu iwe ọ̀rọ ọjọ awọn ọba Israeli.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 14