Nitoriti Oluwa yio kọlu Israeli bi a ti imì iye ninu omi, yio si fa Israeli tu kuro ni ilẹ rere yi, ti o ti fi fun awọn baba wọn, yio si fọ́n wọn ka kọja odò na, nitoriti nwọn ṣe ere oriṣa wọn, nwọn si nru ibinu Oluwa.