Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 11:6-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Solomoni si ṣe buburu niwaju Oluwa, kò si tọ̀ Oluwa lẹhin ni pipé gẹgẹ bi Dafidi baba rẹ̀.

7. Nigbana ni Solomoni kọ́ ibi giga kan fun Kemoṣi, irira Moabu, lori oke ti mbẹ niwaju Jerusalemu, ati fun Moleki, irira awọn ọmọ Ammoni.

8. Bẹ̃li o si ṣe fun gbogbo awọn ajeji obinrin rẹ̀, awọn ti nsun turari, ti nwọn si nrubọ fun oriṣa wọn.

9. Oluwa si binu si Solomoni, nitori ọkàn rẹ̀ yipada kuro lọdọ Oluwa Ọlọrun Israeli, ti o ti fi ara hàn a lẹrinmeji.

10. Ti o si paṣẹ fun u nitori nkan yi pe, Ki o má ṣe tọ̀ awọn ọlọrun miran lẹhin: ṣugbọn kò pa eyiti Oluwa fi aṣẹ fun u mọ́.

11. Nitorina Oluwa wi fun Solomoni pe, Nitori bi iwọ ti ṣe nkan yi, ti iwọ kò si pa majẹmu mi, ati aṣẹ mi mọ́, ti mo ti pa laṣẹ fun ọ, ni yiya emi o fà ijọba rẹ ya kuro lọwọ rẹ, emi o si fi i fun iranṣẹ rẹ.

12. Ṣugbọn emi ki yio ṣe e li ọjọ rẹ, nitori Dafidi baba rẹ; emi o fà a ya kuro lọwọ ọmọ rẹ.

13. Kiki pe emi kì yio fà gbogbo ijọba na ya; emi o fi ẹyà kan fun ọmọ rẹ, nitori Dafidi iranṣẹ mi, ati nitori Jerusalemu ti mo ti yàn.

14. Oluwa si gbe ọta kan dide si Solomoni, Hadadi, ara Edomu: iru-ọmọ ọba li on iṣe ni Edomu.

15. O si ṣe, nigbati Dafidi wà ni Edomu, ati ti Joabu olori-ogun goke lọ lati sìn awọn ti a pa, nigbati o pa gbogbo ọkunrin ni Edomu.

16. Nitori oṣù mẹfa ni Joabu fi joko nibẹ ati gbogbo Israeli, titi o fi ké gbogbo ọkunrin kuro ni Edomu:

17. Hadadi si sá, on ati awọn ara Edomu ninu awọn iranṣẹ baba rẹ̀ pẹlu rẹ̀, lati lọ si Egipti; ṣugbọn Hadadi wà li ọmọde.

18. Nwọn si dide kuro ni Midiani, nwọn si wá si Parani; nwọn si mu enia pẹlu wọn lati Parani wá: nwọn si wá si Egipti, sọdọ Farao ọba Egipti, o si fun u ni ile kan, o si yàn onjẹ fun u, o si fun u ni ilẹ.

19. Hadadi si ri oju-rere pupọ̀ niwaju Farao, o si fun u li arabinrin aya rẹ̀, li aya, arabinrin Tapenesi, ayaba.

20. Arabinrin Tapenesi si bi Genubati ọmọ rẹ̀ fun u, Tapenesi si já a li ẹnu ọmu ni ile Farao: Genubati si wà ni ile Farao lãrin awọn ọmọ Farao,

21. Nigbati Hadadi si gbọ́ ni Egipti pe, Dafidi sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, ati pe Joabu olori-ogun si kú, Hadadi si wi fun Farao pe, rán mi lọ, ki emi ki o le lọ si ilu mi.

22. Nigbana ni Farao wi fun u pe, ṣugbọn kini iwọ ṣe alaini lọdọ mi, si kiyesi i, iwọ nwá ọ̀na lati lọ si ilu rẹ? O si wipe: Kò si nkan: ṣugbọn sa jẹ ki emi ki o lọ.

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 11