Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

1. A. Ọba 1:21-38 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Yio si ṣe, nigbati oluwa mi ọba ba sùn pẹlu awọn baba rẹ̀, a o si kà emi ati Solomoni ọmọ mi si ẹlẹṣẹ̀.

22. Si wò o, bi o si ti mba ọba sọ̀rọ lọwọ, Natani woli si wọle.

23. Nwọn si sọ fun ọba pe, Wò o, Natani woli. Nigbati o si wá siwaju ọba, o wolẹ̀, o si dojubolẹ.

24. Natani si wipe, oluwa mi, ọba! iwọ ha wipe, Adonijah ni yio jọba lẹhin mi ati pe, on o si joko lori itẹ mi bi?

25. Nitori o sọkalẹ lọ loni, o si pa malu ati ẹran ọlọra, ati agùtan li ọ̀pọ-lọpọ, o si pè gbogbo awọn ọmọ ọba, ati awọn balogun, ati Abiatari alufa; si wò o, nwọn njẹ, nwọn si nmu niwaju rẹ̀, nwọn si nwipe, Ki Adonijah ọba ki o pẹ.

26. Ṣugbọn emi, emi iranṣẹ rẹ, ati Sadoku alufa, ati Benaiah ọmọ Jehoiada, ati Solomoni, iranṣẹ rẹ, ni kò pè.

27. Nkan yi ti ọdọ oluwa mi ọba wá bi? iwọ kò si fi ẹniti yio joko lori itẹ oluwa mi ọba lẹhin rẹ̀ hàn iranṣẹ rẹ?

28. Dafidi, ọba si dahùn o si wipe, Ẹ pè Batṣeba fun mi. On si wá siwaju ọba, o si duro niwaju ọba,

29. Ọba si bura, o si wipe, Bi Oluwa ti wà, ẹniti o ti rà ọkàn mi pada kuro ninu gbogbo ìṣẹ́.

30. Gẹgẹ bi mo ti fi Oluwa, Ọlọrun Israeli bura fun ọ, wipe, Nitõtọ Solomoni, ọmọ rẹ, yio jọba lẹhin mi, on o si joko lori itẹ mi ni ipò mi, bẹ̃ni emi o ṣe loni yi dandan.

31. Batṣeba si foribalẹ, o si bọ̀wọ fun ọba, o si wipe, Ki oluwa mi, Dafidi ọba ki o pẹ titi lai.

32. Dafidi ọba wipe, Ẹ pè Sadoku alufa fun mi, ati Natani woli, ati Benaiah ọmọ Jehoiada. Nwọn si wá siwaju ọba.

33. Ọba si wi fun wọn pe, Ẹ mu awọn iranṣẹ oluwa nyin, ki ẹ si mu ki Solomoni ọmọ mi ki o gùn ibãka mi, ki ẹ si mu sọkalẹ wá si Gihoni.

34. Ki ẹ si jẹ ki Sadoku, alufa, ati Natani woli, fi ororo yàn a nibẹ̀ li ọba lori Israeli: ki ẹ si fun fère, ki ẹ si wipe; Ki Solomoni ọba ki o pẹ!

35. Ki ẹ si goke tọ̀ ọ lẹhin, ki o si wá, ki o si joko lori itẹ mi; on o si jọba ni ipò mi: emi si pa a laṣẹ lati jẹ olori Israeli ati Juda.

36. Benaiah ọmọ Jehoiada, si da ọba lohùn, o si wipe, Amin: Oluwa, Ọlọrun ọba oluwa mi, wi bẹ̃ pẹlu.

37. Bi Oluwa ti wà pẹlu oluwa mi ọba, gẹgẹ bẹ̃ni ki o wà pẹlu Solomoni, ki o si ṣe itẹ rẹ̀ ki o pọ̀ jù itẹ oluwa mi, Dafidi ọba lọ.

38. Sadoku alufa, ati Natani woli, ati Benaiah, ọmọ Jehoiada, ati awọn ara Kereti ati Peleti si sọkalẹ, nwọn si mu ki Solomoni ki o gùn ibãka Dafidi ọba, nwọn si mu u wá si Gihoni,

Ka pipe ipin 1. A. Ọba 1