Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hos 5:4-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Iṣe wọn kì o jọ̀wọ wọn lati yipadà si Ọlọrun wọn: nitori ẹmi agbère wà lãrin wọn, nwọn kò si mọ̀ Oluwa.

5. A si rẹ̀ ogo Israeli silẹ loju ara rẹ̀; nitorina ni Israeli ati Efraimu yio ṣubu ninu aiṣedẽde wọn, Juda yio si ṣubu pẹlu wọn.

6. Nwọn o lọ ti awọn ti agbo-ẹran wọn ati ọ̀wọ ẹran wọn lati wá Oluwa: ṣugbọn nwọn kì o ri i, on ti fà ara rẹ̀ sẹhìn kuro lọdọ wọn.

7. Nwọn ti hùwa arekerekè si Oluwa: nitori nwọn ti bi ajèji ọmọ: nisisiyi li oṣù titun yio jẹ wọn run, pẹlu ipin wọn.

8. Ẹ fun korneti ni Gibea, ati ipè ni Rama; kigbe kikan ni Bet-afeni, lẹhìn rẹ, iwọ Benjamini.

9. Efraimu yio di ahoro li ọjọ ibawi: ninu awọn ẹyà Israeli li emi ti fi ohun ti o wà nitõtọ hàn.

10. Awọn olori Juda dàbi awọn ti o yẹ̀ oju àla: lara wọn li emi o tú ibinu mi si bi omi.

11. A tẹ̀ ori Efraimu ba, a si ṣẹgun rẹ̀ ninu idajọ, nitoriti on mọ̃mọ̀ tẹ̀le ofin na.

12. Nitorina ni emi o ṣe dabi kòkoro aṣọ si Efraimu, ati si ile Juda bi idin.

Ka pipe ipin Hos 5