Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hag 2:13-23 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Hagai si wipe, Bi ẹnikan ti o ba jẹ alaimọ́ nipa okú ba fi ara kan ọkan ninu wọnyi, yio ha jẹ alaimọ́? Awọn alufa si dahùn wipe, Yio jẹ alaimọ́.

14. Nigbana ni Hagai dahùn o si wipe, Bẹ̃ni enia wọnyi ri, bẹ̃ si ni orilẹ-ède yi ri niwaju mi, li Oluwa wi; bẹ̃ si li olukuluku iṣẹ ọwọ wọn; eyiti nwọn si fi rubọ nibẹ̀ jẹ alaimọ́.

15. Njẹ nisisiyi, mo bẹ̀ nyin, ẹ rò lati oni yi de atẹhìnwa, ki a to fi okuta kan le ori ekeji ninu tempili Oluwa;

16. Lati ọjọ wọnni wá, nigbati ẹnikan bã de ibi ile ogun, mẹwa pere ni: nigbati ẹnikan ba de ibi ifunti lati bã gbọ́n ãdọta akoto ninu ifunti na, ogún pere ni.

17. Mo fi ìrẹdanù ati imúwòdu ati yìnyin lù nyin ninu gbogbo iṣẹ ọwọ nyin: ṣugbọn ẹnyin kò yipadà sọdọ mi, li Oluwa wi.

18. Nisisiyi ẹ rò lati oni lọ de atẹhìnwa, lati ọjọ ikẹrinlelogun oṣù kẹsan, ani lati ọjọ ti a ti fi ipilẹ tempili Oluwa sọlẹ, ro o.

19. Eso ha wà ninu abà bi? lõtọ, àjara, ati igi òpọtọ, ati pomegranate, ati igi olifi, kò iti so sibẹ̀sibẹ̀: lati oni lọ li emi o bukún fun nyin.

20. Ọ̀rọ Oluwa si tún tọ̀ Hagai wá li ọjọ kẹrinlelogun oṣù na pe,

21. Sọ fun Serubbabeli, bãlẹ Juda, pe, emi o mì awọn ọrun ati aiye;

22. Emi o si bì itẹ awọn ijọba ṣubu, emi o si pa agbara ijọba keferi run; emi o si doju awọn kẹkẹ́ de, ati awọn ti o gùn wọn; ati ẹṣin ati awọn ẹlẹṣin yio wá ilẹ; olukuluku nipa idà arakunrin rẹ̀.

23. Li ọjọ na, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, li emi o mu ọ, Iwọ Serubbabeli, iranṣẹ mi, ọmọ Ṣealtieli, li Oluwa wi, emi o si sọ ọ di oruka edídi kan: nitoriti mo ti yàn ọ, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

Ka pipe ipin Hag 2