Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 8:10-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Bẹ̃ni mo wọle, mo si ri; si kiye si i, gbogbo aworan ohun ti nrakò, ati ẹranko irira, ati gbogbo oriṣa ile Israeli li a yá li aworan lara ogiri yika kiri.

11. Adọrin ọkunrin ninu awọn agbà ile Israeli si duro niwaju wọn, Jaasania ọmọ Ṣafani si duro lãrin wọn, olukuluku pẹlu awo turari lọwọ rẹ̀; ẹ̃fin ṣiṣu dùdu ti turari si goke lọ.

12. Nigbana li o si wi fun mi pe, Ọmọ enia iwọ ri ohun ti awọn agbà ile Israeli nṣe li okunkùn, olukuluku ninu iyará oriṣa tirẹ̀? nitori nwọn wipe, Oluwa kò ri wa; Oluwa ti kọ̀ aiye silẹ.

13. O si wi fun mi pe, Tun yipada, iwọ o si ri ohun irira ti o tobi jù yi ti nwọn nṣe.

14. Nigbana li o mu mi wá si ilẹkun ẹnu-ọ̀na ile Oluwa, ti o wà nihà ariwa; si kiye si i, awọn obinrin joko nwọn nsọkun fun Tammusi.

15. Nigbana li o sọ fun mi pe, Iwọ ri eyi, Iwọ ọmọ enia? tun yipada, iwọ o si ri ohun irira ti o tobi ju wọnyi lọ.

16. O si mu mi wá si inu agbala ile Oluwa, si kiye si i, li ẹnu-ọ̀na tempili Oluwa, lãrin iloro ati pẹpẹ, ni iwọ̀n ọkunrin mẹ̃dọgbọ̀n wà, ti nwọn kẹ̀hin si tẹmpili Oluwa, ti nwọn si kọju si ila-õrùn; nwọn si foribalẹ fun õrun si ila-õrun.

17. Nigbana li o wi fun mi pe, Iwọ ri eyi, ọmọ enia? ohun kekere ni fun ile Juda lati ṣe ohun irira ti nwọn nṣe nihin? nitori nwọn fi ìwa-ipa kún ilẹ na, nwọn si ti pada lati mu mi binu, si kiye si i, nwọn tẹ̀ ẹka-igi bọ imú wọn.

18. Emi pẹlu yio si fi irúnu ba wọn lò: oju mi kì yio dasi, bẹ̃li emi kì yio ṣãnu: ati bi o tilẹ ṣepe nwọn fi ohùn rara kigbe li eti mi, sibẹ emi kì yio gbọ́ ti wọn.

Ka pipe ipin Esek 8