Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 46:3-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Enia ilẹ na yio si ma sìn ni ilẹkùn ẹnu-ọ̀na yi niwaju Oluwa ni ọjọ isimi, ati ni oṣù titun.

4. Ọrẹ-ẹbọ sisun ti olori na yio rú si Oluwa ni ọjọ isimi, yio jẹ ọdọ-agutan mẹfa alailabawọn, ati agbò kan alailabàwọn.

5. Ati ọrẹ ẹbọ jijẹ yio jẹ efà kan fun agbò kan, ati ọrẹ-ẹbọ jijẹ fun ọdọ-agutan ẹbùn ọwọ́ rẹ̀, ati hini ororo kan fun efa kan.

6. Ati li ọjọ oṣù titun, ẹgbọ̀rọ malũ kan ailabawọn, ati ọdọ-agutan mẹfa, ati agbò kan: nwọn o wà lailabàwọn.

7. Yio si pèse ọrẹ-ẹbọ jijẹ, efa fun ẹgbọ̀rọ akọ malu kan, ati efa kan fun agbò kan, ati fun awọn ọdọ-agutan gẹgẹ bi ọwọ́ rẹ̀ ba ti to, ati hini ororo kan fun efa kan.

8. Nigbati olori na yio ba si wọle, ọ̀na iloro ẹnu-ọ̀na ni yio ba wọle, yio si ba ọ̀na rẹ̀ jade.

9. Nigbati enia ilẹ na yio ba si wá siwaju Oluwa ni awọn apejọ ọ̀wọ, ẹniti o ba ba ọ̀na ẹnu-ọ̀na ariwa wọle lati sìn, yio ba ọ̀na ẹnu-ọ̀na gusu jade; ẹniti o ba si ba ọ̀na ẹnu-ọ̀na gusu wọle yio si ba ọ̀na ẹnu-ọ̀na ariwa jade; kì yio ba ọ̀na ẹnu-ọ̀na ti o ba wọle jade, ṣugbọn yio jade lodi keji.

10. Ati olori ti o wà lãrin wọn, nigbati nwọn ba wọle, yio wọle; nigbati nwọn ba si jade, yio jade.

11. Ati ninu awọn asè ati ninu awọn ajọ, ọrẹ-ẹbọ jijẹ yio jẹ efa kan fun ẹgbọ̀rọ akọ-malu kan, ati efa kan fun agbò kan, ati fun awọn ọdọ-agutan ẹbùn ọwọ́ rẹ̀, ati hini ororo kan fun efa kan.

12. Nigbati olori na yio ba si pèse ọrẹ-ẹbọ sisun atinuwá, tabi ọrẹ-ẹbọ idupẹ atinuwá fun Oluwa, ẹnikan yio si ṣi ilẹkun ti o kọjusi ila-õrun fun u, yio si pèse ọrẹ-ẹbọ sisun rẹ̀, ati ẹbọ idupẹ rẹ̀, bi o ti ṣe li ọjọ-isimi: yio si jade; ati lẹhin ijadelọ rẹ̀ ẹnikan yio tì ilẹkun.

13. Li ojojumọ ni iwọ o pèse ọdọ agutan kan alailabawọn ọlọdun kan fun ọrẹ-ẹbọ sisun fun Oluwa: iwọ o ma pèse rẹ̀ lorowurọ̀.

14. Iwọ o si pèse ọrẹ-ẹbọ jijẹ fun u lorowurọ̀, idamẹfa efa, ati idamẹfa hini ororo kan, lati fi pò iyẹfun daradara na; ọrẹ-ẹbọ jijẹ nigbagbogbo nipa aṣẹ lailai fun Oluwa.

15. Bayi ni nwọn o pèse ọdọ-agutan na, ati ọrẹ-ẹbọ jijẹ na, ati ororo na, lojojumọ fun ọrẹ-ẹbọ sisun nigbagbogbo.

16. Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Bi olori na ba fi ẹbùn fun ẹnikẹni ninu awọn ọmọ rẹ̀, ogún rẹ̀ yio jẹ ti awọn ọmọ rẹ̀; yio jẹ ini wọn nipa ijogun.

Ka pipe ipin Esek 46