Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 44:15-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Ṣugbọn awọn alufa awọn Lefi, awọn ọmọ Sadoku, ti o pa ibi-iṣọ ibi mimọ́ mi mọ, nigbati awọn ọmọ Israeli ṣìna kuro lọdọ mi, awọn ni yio sunmọ ọdọ mi lati ṣe iranṣẹ fun mi, nwọn o si duro niwaju mi lati rú ọrá ati ẹjẹ si mi, ni Oluwa Ọlọrun wi:

16. Awọn ni yio wá si ibi-mimọ́ mi, awọn ni o si sunmọ tabili mi, lati ṣe iranṣẹ fun mi, nwọn o si pa ibi-iṣọ́ mi mọ́.

17. Yio si ṣe pe, nigbati nwọn ba wá si ẹnu-ọ̀na agbalá ti inu, nwọn o wọ̀ ẹ̀wu ọ̀gbọ; irun agutan kì yio bọ́ si ara wọn, nigbati nwọn ba nṣe iranṣẹ ni ẹnu-ọ̀na agbalá ti inu, ati ninu ile.

18. Nwọn o si ni filà ọ̀gbọ li ori wọn, ṣòkoto ọ̀gbọ ni nwọn o si wọ̀ ni idí wọn; nwọn kì o si fi ohun ti imuni lãgùn dì amurè.

19. Nigbati nwọn ba si lọ si agbalá ode, ani si agbalá ode sọdọ awọn enia, nwọn o bọ́ ẹ̀wu wọn ti wọn ifi ṣe iranṣẹ, nwọn o si fi wọn si awọn yará mimọ́, nwọn o si wọ̀ ẹ̀wu miran; nwọn kì yio si fi ẹ̀wu wọn sọ awọn enia di mimọ́.

20. Nwọn kì o si fá ori wọn, bẹ̃ni nwọn kì yio jẹ ki irun wọn gbọ̀; ni rirẹ nwọn o rẹ irun ori wọn.

21. Alufa gbogbo kì yio mu ọti-waini, nigbati nwọn ba wá si agbalá ti inu.

22. Nwọn kì yio si fẹ́ opo, tabi ẹniti a tì jade fun aya wọn: ṣugbọn nwọn o fẹ́ wundia lati iru-ọmọ ile Israeli, tabi opo ti o ti ni alufa ri.

23. Nwọn o si kọ́ awọn enia mi ni iyàtọ ti o wà lãrin mimọ́ ati ailọ̀wọ, nwọn o si mu wọn mọ̀ eyiti o wà lãrin aimọ́ ati mimọ́.

24. Ati ni ija, awọn ni yio duro lati ṣe idajọ; nwọn o si dá a ni idajọ mi: nwọn o si pa ofin mi ati aṣẹ mi mọ́ ni gbogbo apejọ mi; nwọn o si yà awọn ọjọ isimi mi si mimọ́.

25. Nwọn kì yio si wá sọdọ okú enia lati sọ ara wọn di aimọ́, ṣugbọn fun baba, tabi fun iya, tabi fun ọmọkunrin, tabi fun ọmọbinrin, fun arakunrin, tabi fun arabinrin ti kò ti ni ọkọ, nwọn le sọ ara wọn di aimọ́.

26. Ati lẹhin iwẹnumọ́ rẹ̀, nwọn o si ká ọjọ meje fun u.

27. Ati li ọjọ ti yio lọ si ibi-mimọ́, si agbalá ti inu, lati ṣe iranṣẹ ni ibi-mimọ́, on o rú ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ni Oluwa Ọlọrun wi.

28. Ati ogún ni yio jẹ fun wọn: emi ni ogún wọn: ẹ kì yio si fun wọn ni ini ni Israeli: emi ni ini wọn.

29. Awọn ni yio jẹ ọrẹ ẹbọ jijẹ, ati ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ọrẹ ẹbọ irekọja; ati gbogbo ohun-egún ni Israeli, yio jẹ́ ti wọn.

30. Ati ikini ninu gbogbo akọ́so nkan gbogbo, olukuluku ọrẹ gbogbo, ninu gbogbo ọrẹ nyin, yio jẹ ti awọn alufa: ẹ o si fi akọ́po iyẹfun nyin fun alufa, ki ibukun le bà le ile rẹ.

Ka pipe ipin Esek 44