Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 43:17-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

17. Ati ijoko ni yio jẹ igbọ̀nwọ mẹrinla ni gigun ati mẹrinla ni ibú ninu igun mẹrẹrin rẹ̀; ati eti rẹ̀ yika yio jẹ́ abọ̀ igbọnwọ; ati isalẹ rẹ̀ yio jẹ igbọnwọ kan yika; atẹgùn rẹ̀ yio si kọjusi iha ila-õrun.

18. O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Eyi ni aṣẹ pẹpẹ na li ọjọ ti nwọn o ṣe e, lati rú ọrẹ ẹbọ sisun lori rẹ̀, ati lati wọ́n ẹ̀jẹ sori rẹ̀.

19. Iwọ o si fi ẹgbọrọ malu, fun ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, fun awọn alufa, awọn Lefi, ti iṣe iru-ọmọ Sadoku, ti nsunmọ mi, lati ṣe iranṣẹ fun mi, ni Oluwa Ọlọrun wi.

20. Iwọ o si mu ninu ẹjẹ rẹ̀, iwọ o si fi si iwo mẹrẹrin rẹ̀, ati si igun mẹrẹrin ijoko na, ati si eti rẹ̀ yika: iwọ o si wẹ̀ ẹ̀ṣẹ rẹ̀ mọ́, iwọ o si ṣe etùtu rẹ̀.

21. Iwọ o si mu ẹgbọrọ malu ti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, on o si sun u ni ibiti a yàn ni ile na lode ibi-mimọ́.

22. Ati ni ọjọ keji iwọ o fi ọmọ ewurẹ alailabawọn rubọ ọrẹ ẹ̀ṣẹ; nwọn o si sọ pẹpẹ na di mimọ́, bi nwọn iti ifi ẹgbọrọ malu sọ ọ di mimọ́.

23. Nigbati iwọ ba ti sọ ọ di mimọ tan, iwọ o fi ẹgbọrọ malu alailabawọn rubọ, ati àgbo alailabawọn lati inu agbo wá.

24. Iwọ o si fi wọn rubọ niwaju Oluwa, awọn alufa yio si dà iyọ̀ si wọn, nwọn o si fi wọn rú ọrẹ ẹbọ sisun si Oluwa.

25. Ọjọ meje ni iwọ o fi pèse obukọ fun ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ lojojumọ: nwọn o si pèse ẹgbọrọ malu pẹlu ati àgbo lati inu agbo wá, ti nwọn ṣe ailabawọn.

26. Ọjọ meje ni nwọn o fi wẹ̀ pẹpẹ, nwọn o si sọ ọ di mimọ́: nwọn o si yà ara wọn sọtọ̀.

Ka pipe ipin Esek 43