Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 40:30-48 Yorùbá Bibeli (YCE)

30. Awọn iloro ti mbẹ yika jẹ igbọnwọ mẹ̃dọgbọ̀n ni gigùn, ati igbọnwọ marun ni ibú.

31. Awọn iloro rẹ̀ mbẹ nihà agbalá ode; igi ọpẹ si mbẹ lara atẹrigbà rẹ̀: abágòke rẹ̀ si ní atẹ̀gun mẹjọ.

32. O si mu mi wá si agbalá ti inu nihà ọ̀na ila-õrun: o si wọ̀n ẹnu-ọ̀na na, gẹgẹ bi iwọn wọnyi.

33. Ati yara kékèké rẹ̀, ati atẹrigbà rẹ̀, ati iloro rẹ̀, jẹ gẹgẹ bi ìwọn wọnyi: ferese si mbẹ ninu rẹ̀ ati ninu awọn iloro rẹ̀ yika: o jẹ ãdọta igbọnwọ ni gigùn, ati igbọnwọ mẹ̃dọgbọn ni ibú.

34. Awọn iloro rẹ̀ mbẹ nihà agbalá ode; igi ọpẹ si mbẹ lara atẹrigbà rẹ̀, nihà ìhin, ati nihà ọ̀hun: abagòke rẹ̀ si ní atẹ̀gun mẹjọ.

35. O si mu mi wá si ẹnu-ọ̀na ariwa, o si wọ̀n ọ gẹgẹ bi ìwọn wọnyi;

36. Awọn yará kékèké rẹ̀, atẹrigbà rẹ̀, ati iloro rẹ̀, ati ferese rẹ̀ yika: gigùn rẹ̀ jẹ ãdọta igbọnwọ, ati ibu rẹ̀ igbọnwọ mẹ̃dọgbọ̀n.

37. Ati atẹrigba rẹ̀ mbẹ niha agbalá ode; igi ọpẹ si mbẹ lara atẹrigba rẹ̀, niha ìhin, ati niha ọ̀hun: abagòke rẹ̀ si ní atẹ̀gun mẹjọ.

38. Ati yàra ati abáwọle rẹ̀ wà nihà atẹrigbà ẹnu-ọ̀na na, nibiti nwọn ima wẹ̀ ọrẹ ẹbọ sisun.

39. Ati ni iloro ẹnu-ọ̀na na tabili meji mbẹ nihà ìhin, ati tabili meji nihà ọ̀hun, lati ma pa ẹran ẹbọ sisun, ati ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ọrẹ ẹbọ irekọja lori wọn.

40. Ati ni ihà ode, bi a ba nlọ si àbáwọle ẹnu-ọ̀na ariwa, ni tabili meji mbẹ; ati nihà miran, ti iṣe iloro ẹnu-ọ̀na, ni tabili meji mbẹ.

41. Tabili mẹrin mbẹ nihà ìhin, tabili mẹrin si mbẹ nihà ọ̀hun, nihà ẹnu-ọ̀na; tabili mẹjọ, lori eyiti nwọn a ma pa ẹran ẹbọ wọn.

42. Tabili mẹrin na si jẹ ti okuta gbigbẹ́ fun ọrẹ ẹbọ sisun, igbọnwọ kan on ãbọ ni gigùn, ati igbọnwọ kan on ãbọ ni ibú, ati igbọnwọ kan ni giga: lori eyiti nwọn a si ma kó ohun-elò wọn le, ti nwọn ifi pa ọrẹ ẹbọ sisun ati ẹran ẹbọ.

43. Ati ninu ni ìwọ ẹlẹnu meji, oníbu atẹlẹwọ kan, ti a kàn mọ ọ yika: ati lori awọn tabili na ni ẹran ọrẹ gbe wà.

44. Ati lode ẹnu-ọ̀na ti inu ni yará awọn akọrin gbe wà, ninu agbala ti inu, ti mbẹ ni ihà ẹnu-ọ̀na ariwa; oju wọn si wà li ọ̀na gusu: ọkan ni iha ẹnu-ọ̀na ila-õrun, oju eyiti mbẹ li ọ̀na ariwa.

45. O si wi fun mi pe, Yàrá yi, ti oju rẹ̀ mbẹ li ọ̀na gusu, ni fun awọn alufa, awọn olutọjú iṣọ ile na.

46. Yará ti oju rẹ̀ mbẹ li ọ̀na ariwa, ni fun awọn alufa, awọn olutọjú iṣọ pẹpẹ na; awọn wọnyi li awọn ọmọ Sadoku ninu awọn ọmọ Lefi, ti nwọn ima sunmọ Oluwa lati ṣe iranṣẹ fun u.

47. O si wọ̀n agbalá na, ọgọrun igbọnwọ ni gigùn, ọgọrun igbọnwọ ni ibú, igun mẹrin lọgbọgba; ati pẹpẹ ti mbẹ niwaju ile na.

48. O si mu mi wá si iloro ile na, o si wọ̀n opo iloro na, igbọnwọ marun nihà ìhin, ati igbọnwọ marun nihà ọ̀hun: ibu ẹnu-ọ̀na na si jẹ igbọnwọ mẹta nihà ìhin, ati igbọnwọ mẹta nihà ọ̀hun.

Ka pipe ipin Esek 40