Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 40:28-42 Yorùbá Bibeli (YCE)

28. O si mu mi wá si agbalá ti inu nipa ẹnu-ọ̀na gusu: o si wọ̀n ẹnu-ọ̀na gusu na gẹgẹ bi ìwọn wọnyi;

29. Ati awọn yará kékèké rẹ̀, ati atẹrigbà rẹ̀, ati iloro rẹ̀, gẹgẹ bi ìwọn wọnyi: ferese pupọ̀ si mbẹ nibẹ ati ni iloro rẹ̀ yika: o jẹ ãdọta igbọnwọ ni gigùn, igbọnwọ mẹ̃dọgbọn ni ibú.

30. Awọn iloro ti mbẹ yika jẹ igbọnwọ mẹ̃dọgbọ̀n ni gigùn, ati igbọnwọ marun ni ibú.

31. Awọn iloro rẹ̀ mbẹ nihà agbalá ode; igi ọpẹ si mbẹ lara atẹrigbà rẹ̀: abágòke rẹ̀ si ní atẹ̀gun mẹjọ.

32. O si mu mi wá si agbalá ti inu nihà ọ̀na ila-õrun: o si wọ̀n ẹnu-ọ̀na na, gẹgẹ bi iwọn wọnyi.

33. Ati yara kékèké rẹ̀, ati atẹrigbà rẹ̀, ati iloro rẹ̀, jẹ gẹgẹ bi ìwọn wọnyi: ferese si mbẹ ninu rẹ̀ ati ninu awọn iloro rẹ̀ yika: o jẹ ãdọta igbọnwọ ni gigùn, ati igbọnwọ mẹ̃dọgbọn ni ibú.

34. Awọn iloro rẹ̀ mbẹ nihà agbalá ode; igi ọpẹ si mbẹ lara atẹrigbà rẹ̀, nihà ìhin, ati nihà ọ̀hun: abagòke rẹ̀ si ní atẹ̀gun mẹjọ.

35. O si mu mi wá si ẹnu-ọ̀na ariwa, o si wọ̀n ọ gẹgẹ bi ìwọn wọnyi;

36. Awọn yará kékèké rẹ̀, atẹrigbà rẹ̀, ati iloro rẹ̀, ati ferese rẹ̀ yika: gigùn rẹ̀ jẹ ãdọta igbọnwọ, ati ibu rẹ̀ igbọnwọ mẹ̃dọgbọ̀n.

37. Ati atẹrigba rẹ̀ mbẹ niha agbalá ode; igi ọpẹ si mbẹ lara atẹrigba rẹ̀, niha ìhin, ati niha ọ̀hun: abagòke rẹ̀ si ní atẹ̀gun mẹjọ.

38. Ati yàra ati abáwọle rẹ̀ wà nihà atẹrigbà ẹnu-ọ̀na na, nibiti nwọn ima wẹ̀ ọrẹ ẹbọ sisun.

39. Ati ni iloro ẹnu-ọ̀na na tabili meji mbẹ nihà ìhin, ati tabili meji nihà ọ̀hun, lati ma pa ẹran ẹbọ sisun, ati ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ọrẹ ẹbọ irekọja lori wọn.

40. Ati ni ihà ode, bi a ba nlọ si àbáwọle ẹnu-ọ̀na ariwa, ni tabili meji mbẹ; ati nihà miran, ti iṣe iloro ẹnu-ọ̀na, ni tabili meji mbẹ.

41. Tabili mẹrin mbẹ nihà ìhin, tabili mẹrin si mbẹ nihà ọ̀hun, nihà ẹnu-ọ̀na; tabili mẹjọ, lori eyiti nwọn a ma pa ẹran ẹbọ wọn.

42. Tabili mẹrin na si jẹ ti okuta gbigbẹ́ fun ọrẹ ẹbọ sisun, igbọnwọ kan on ãbọ ni gigùn, ati igbọnwọ kan on ãbọ ni ibú, ati igbọnwọ kan ni giga: lori eyiti nwọn a si ma kó ohun-elò wọn le, ti nwọn ifi pa ọrẹ ẹbọ sisun ati ẹran ẹbọ.

Ka pipe ipin Esek 40