Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 40:23-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

23. Ati ẹnu-ọ̀na agbala inu ti o kọju si ẹnu-ọ̀na ti ariwa, ati ti ila-õrun; o si wọ̀n lati ẹnu-ọ̀na de ẹnu-ọ̀na, ọgọrun igbọnwọ.

24. O si mu mi lọ si ọ̀na gusù, si kiye si i, ẹnu-ọ̀na kan mbẹ li ọ̀na gusù: o si wọ̀n awọn atẹrigba wọn, ati ìloro wọn gẹgẹ bi ìwọn wọnyi.

25. Fèrese pupọ si mbẹ ninu rẹ̀ ati ninu iloro wọn yika, bi ferese wọnni: gigùn rẹ̀ jẹ ãdọta igbọnwọ, ibú rẹ̀ jẹ igbọnwọ mẹ̃dọgbọn.

26. Atẹ̀gun meje ni mbẹ lati bá gùn oke rẹ̀, ati awọn iloro rẹ̀ si mbẹ niwaju wọn: o si ni igi ọpẹ, ọkan nihà ìhin, ati ọkan nihà ọhún, lara awọn atẹrigbà rẹ̀.

27. Ati ẹnu-ọ̀na agbalá ti inu mbẹ li ọ̀na gusu; o si wọ̀n lati ẹnu-ọ̀na de ẹnu-ọ̀na li ọ̀na gusu, ọgọrun igbọnwọ.

28. O si mu mi wá si agbalá ti inu nipa ẹnu-ọ̀na gusu: o si wọ̀n ẹnu-ọ̀na gusu na gẹgẹ bi ìwọn wọnyi;

29. Ati awọn yará kékèké rẹ̀, ati atẹrigbà rẹ̀, ati iloro rẹ̀, gẹgẹ bi ìwọn wọnyi: ferese pupọ̀ si mbẹ nibẹ ati ni iloro rẹ̀ yika: o jẹ ãdọta igbọnwọ ni gigùn, igbọnwọ mẹ̃dọgbọn ni ibú.

30. Awọn iloro ti mbẹ yika jẹ igbọnwọ mẹ̃dọgbọ̀n ni gigùn, ati igbọnwọ marun ni ibú.

Ka pipe ipin Esek 40