Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 4:2-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Ki o si dótì i, ki o si mọ ile iṣọ tì i, ki o si mọ odi tì i, ki o si gbe ogun si i, ki o si to õlù yi i ka.

3. Mu awo irin kan, ki o si gbe e duro bi odi irin lãrin rẹ ati ilu na: ki o si kọju si i, a o si dótì i, iwọ o si dótì i. Eyi o jẹ àmi si ile Israeli.

4. Fi iha osì rẹ dubulẹ, ki o si fi ẹ̀ṣẹ ile Israeli sori rẹ̀: gẹgẹ bi iye ọjọ ti iwọ o dubulẹ sori rẹ̀ ni iwọ o ru ẹ̀ṣẹ wọn.

5. Nitori mo ti fi ọdun ẹ̀ṣẹ wọn le ọ lori, gẹgẹ bi iye ọjọ na, ẹwa-di-ni-irinwo ọjọ: bẹ̃ni iwọ o ru ẹ̀ṣẹ ile Israeli.

6. Nigbati iwọ ba si pari wọn, tun fi ẹgbẹ́ rẹ ọtún dubulẹ, iwọ o si ru ẹ̀ṣẹ ile Juda li ogoji ọjọ: mo ti yàn ọjọ kan fun ọdun kan fun ọ.

7. Nitorina iwọ o kọju si didótì Jerusalemu, iwọ ki yio si bo apá rẹ, iwọ o si sọ asọtẹlẹ si i.

8. Si kiyesi i, emi o fi idè le ara rẹ, iwọ ki yio si yipada lati ihà kan de ekeji, titi iwọ o fi pari gbogbo ọjọ didotì rẹ.

9. Si mu alikama, ati ọka bàba, erẽ ati lentile ati milleti, ati ẹwẹ, fi wọn sinu ikoko kan, ki o si fi wọn ṣe akara, gẹgẹ bi iye ọjọ ti iwọ o dubulẹ li ẹgbẹ́ rẹ, ẹwa-di-ni-irinwo ọjọ ni iwọ o jẹ ninu rẹ̀.

10. Iwọ o si jẹ onjẹ rẹ nipa ìwọn, ogún ìwọn ṣekeli li ọjọ kan, lati akoko de akoko ni iwọ o jẹ ẹ.

11. Iwọ o si mu omi nipa ìwọn, idamẹfa oṣuwọ̀n hini kan: lati akoko de akoko ni iwọ o mu u.

Ka pipe ipin Esek 4