Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 4:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. IWỌ, ọmọ enia, mu awo kan, ki o si fi si iwaju rẹ, ki o si ṣe aworan ilu Jerusalemu sinu rẹ̀.

2. Ki o si dótì i, ki o si mọ ile iṣọ tì i, ki o si mọ odi tì i, ki o si gbe ogun si i, ki o si to õlù yi i ka.

3. Mu awo irin kan, ki o si gbe e duro bi odi irin lãrin rẹ ati ilu na: ki o si kọju si i, a o si dótì i, iwọ o si dótì i. Eyi o jẹ àmi si ile Israeli.

4. Fi iha osì rẹ dubulẹ, ki o si fi ẹ̀ṣẹ ile Israeli sori rẹ̀: gẹgẹ bi iye ọjọ ti iwọ o dubulẹ sori rẹ̀ ni iwọ o ru ẹ̀ṣẹ wọn.

5. Nitori mo ti fi ọdun ẹ̀ṣẹ wọn le ọ lori, gẹgẹ bi iye ọjọ na, ẹwa-di-ni-irinwo ọjọ: bẹ̃ni iwọ o ru ẹ̀ṣẹ ile Israeli.

Ka pipe ipin Esek 4