Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 38:2-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Ọmọ enia, kọ oju rẹ si Gogu, ilẹ Magogu, olori Roṣi, Meṣeki, ati Tubali, si sọtẹlẹ si i,

3. Si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi dojukọ ọ, iwọ Gogu, olori Roṣi, Meṣeki, ati Tubali:

4. Emi o si dá ọ padà, emi o si fi ìwọ kọ́ ọ li ẹ̀rẹkẹ́, emi o si mu ọ jade wá, ati gbogbo ogun rẹ, ẹṣin ati ẹlẹṣin, gbogbo wọn li a wọ̀ laṣọ daradara, ani ẹgbẹ́ nla pẹlu apata on asà, gbogbo wọn dì idà mu:

5. Persia, Etiopia, ati Libia pẹlu wọn; gbogbo wọn pẹlu asà on akoro:

6. Gomeri, ati gbogbo ogun rẹ̀; ile Togarma ti ihà ariwa, ati gbogbo ogun rẹ̀: enia pupọ̀ pẹlu rẹ̀.

7. Iwọ mura silẹ, si mura fun ara rẹ, iwọ, ati gbogbo ẹgbẹ́ rẹ ti a gbajọ fun ọ, ki iwọ jẹ alãbo fun wọn.

8. Lẹhìn ọjọ pupọ̀ li a o bẹ̀ ọ wò: li ọdun ikẹhìn, iwọ o wá si ilẹ ti a gbà padà lọwọ idà, ti a si kojọ pọ̀ kuro lọdọ enia pupọ̀, lori oke-nla Israeli, ti iti ma di ahoro: ṣugbọn a mu u jade kuro ninu awọn orilẹ-ède, nwọn o si ma gbe li ailewu, gbogbo wọn.

9. Iwọ o goke wá, iwọ o si de bi ijì, iwọ o dabi awọsanma lati bò ilẹ, iwọ, ati gbogbo awọn ogun rẹ, ati ọ̀pọlọpọ enia pẹlu rẹ.

10. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; yio si ṣe pe nigbakanna ni nkan yio sọ si ọ̀kàn rẹ, iwọ o si rò èro ibi kan.

11. Iwọ o si wipe, emi o goke lọ si ilẹ ileto ti kò ni odi: emi o tọ̀ awọn ti o wà ni isimi lọ, ti nwọn ngbe laibẹ̀ru, ti gbogbo wọn ngbe laisi odi, ti nwọn kò si ni agbarà-irin tabi ẹnu-odi,

12. Lati lọ kó ikogun, ati lati lọ mu ohun ọdẹ; lati yi ọwọ́ rẹ si ibi ahoro wọnni ti a tẹ̀do nisisiyi, ati si enia ti a kojọ lati inu awọn orilẹ-ède wá, awọn ti o ti ni ohun-ọ̀sin ati ẹrù, ti ngbe oke ilẹ na.

Ka pipe ipin Esek 38