Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 36:10-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Emi o si mu enia bi si i lori nyin, gbogbo ile Israeli, ani gbogbo rẹ̀: awọn ilu yio si ni olugbe, a o si kọ́ ibi ti o di ahoro:

11. Emi o si mu enia ati ẹranko bi si i lori nyin; nwọn o si pọ̀ si i, nwọn o si rẹ̀: emi o si mu nyin joko ni ibugbe nyin, bi ti atijọ, emi o si ṣe si nyin jù igbà ibẹ̀rẹ nyin lọ: ẹnyin o si mọ̀ pe, emi li Oluwa.

12. Nitõtọ, emi o mu ki enia rìn lori nyin, ani Israeli enia mi; nwọn o si ni ọ, iwọ o si jẹ iní wọn, iwọ kì yio si gbà wọn li ọmọ mọ lati isisiyi lọ.

13. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitori nwọn wi fun nyin, pe, Iwọ jẹ enia run, o si ti gbà awọn orilẹ-ède li ọmọ;

14. Nitorina iwọ kì yio jẹ enia run mọ, bẹ̃ni iwọ kì yio gbà awọn orilẹ rẹ li ọmọ mọ, li Oluwa Ọlọrun wi.

15. Bẹ̃ni emi kì yio mu ki enia gbọ́ ìtiju awọn keferi ninu rẹ mọ, bẹ̃ni iwọ kì yio rù ẹ̀gan awọn orilẹ-ède mọ, bẹ̃ni iwọ kì yio mu ki orilẹ-ẹ̀de rẹ ṣubu mọ, li Oluwa Ọlọrun wi.

16. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,

17. Ọmọ enia, nigbati ile Israeli ngbe ilẹ ti wọn; nwọn bà a jẹ nipa ọ̀na wọn, ati nipa iṣe wọn: ọ̀na wọn loju mi dabi aimọ́ obinrin ti a mu kuro.

18. Nitorina emi fi irúnu mi si ori wọn, nitori ẹ̀jẹ ti wọn ti ta sori ilẹ na, ati nitori ere wọn ti wọn ti fi bà a jẹ.

19. Emi si ti tú wọn ká sãrin awọn keferi, a si fọn wọn ká si gbogbo ilẹ: emi dá wọn lẹjọ, gẹgẹ bi ọ̀na wọn, ati gẹgẹ bi iṣe wọn.

20. Nigbati awọn si wọ̀ inu awọn keferi, nibiti nwọn lọ, nwọn bà orukọ mimọ́ mi jẹ, nigbati nwọn wi fun wọn pe, Awọn wọnyi li enia Oluwa, nwọn si ti jade kuro ni ilẹ rẹ̀.

21. Ṣugbọn ãnu orukọ mimọ́ mi ṣe mi, ti ile Israeli ti bajẹ lãrin awọn keferi, nibiti nwọn lọ.

22. Nitorina sọ fun ile Israeli, pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Ile Israeli, emi kò ṣe eyi nitori ti nyin, ṣugbọn fun orukọ mimọ́ mi, ti ẹnyin ti bajẹ lãrin awọn keferi, nibiti ẹnyin lọ.

Ka pipe ipin Esek 36