Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 36:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. ATI iwọ, ọmọ enia, sọtẹlẹ si awọn oke Israeli, si wipe, Ẹnyin oke Israeli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa:

2. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Nitori ti ọta ti wi si nyin pe, Aha, ani ibi giga igbãni jẹ tiwa ni ini:

3. Nitorina sọtẹlẹ, ki o si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, pe, Nitõtọ nitori nwọn ti sọ ọ di ahoro, ti nwọn si gbe ọ mì niha gbogbo, ki ẹnyin ba le jẹ ini fun awọn keferi iyokù, ti a mu nyin si ẹnu, ti ẹnyin si jasi ẹ̀gan awọn enia:

4. Nitorina, ẹnyin oke Israeli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa Ọlọrun; Bayi li Oluwa Ọlọrun wi fun awọn oke-nla, ati fun awọn oke kékèké, fun awọn odò, ati fun awọn afonifoji, fun ibi idahoro, ati fun awọn ilu ti a kọ̀ silẹ, ti o di ijẹ ati iyọsùtisi fun awọn keferi iyokù ti o yika kiri;

5. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Nitõtọ ninu iná owu mi li emi ti sọ̀rọ si awọn keferi iyokù, ati si gbogbo Idumea, ti o ti fi ayọ̀ inu wọn gbogbo yàn ilẹ mi ni iní wọn, pẹlu àrankan inu, lati ta a nù fun ijẹ.

Ka pipe ipin Esek 36