Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 34:12-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Gẹgẹ bi oluṣọ́ agutan iti iwá ọwọ́-ẹran rẹ̀ ri, li ọjọ ti o wà lãrin awọn agutan rẹ̀ ti o fọnka, bẹ̃li emi o wá agutan mi ri, emi o si gbà wọn nibi gbogbo ti wọn ti fọnka si, li ọjọ kũkũ ati okùnkun biribiri.

13. Emi o si mu wọn jade kuro ninu awọn orilẹ-ède, emi o si kó wọn jọ lati ilẹ gbogbo, emi o si mu wọn wá si ilẹ ara wọn, emi o si bọ́ wọn lori oke Israeli, lẹba odò, ati ni ibi gbigbé ni ilẹ na.

14. Emi o bọ́ wọn ni pápa oko daradara ati lori okè giga Israeli ni agbo wọn o wà: nibẹ ni nwọn o dubulẹ ni agbo daradara, pápa oko ọlọ́ra ni nwọn o si ma jẹ lori oke Israeli.

15. Emi o bọ́ ọwọ́-ẹran mi, emi o si mu ki nwọn dubulẹ, li Oluwa Ọlọrun wi.

16. Emi o wá eyiti o sọnu lọ, emi o si mu eyiti a lé lọ pada bọ̀, emi o si dì eyiti a ṣá lọ́gbẹ, emi o mu eyiti o ṣaisan li ara le; ṣugbọn emi o run eyiti o sanra ati eyiti o lagbara; emi o fi idajọ bọ́ wọn.

17. Bi o ṣe ti nyin, Ẹnyin ọwọ́-ẹran mi, bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i emi o ṣe idajọ lãrin ẹran ati ẹran, lãrin àgbo ati obukọ.

18. Ohun kekere ni li oju nyin ti ẹ ti jẹ oko daradara, ṣugbọn ẹnyin si fi ẹsẹ tẹ̀ oko iyokù mọlẹ, ati ti ẹ ti mu ninu omi jijìn, ṣugbọn ẹ si fi ẹsẹ ba eyi ti o kù jẹ?

19. Bi o ṣe ti ọwọ́-ẹran mi ni, nwọn jẹ eyiti ẹ ti fi ẹsẹ nyin tẹ̀ mọlẹ; nwọn si mu eyiti ẹ ti fi ẹsẹ nyin bajẹ.

20. Nitorina, bayi li Oluwa Ọlọrun wi fun wọn, Kiyesi, emi, ani emi, o ṣe idajọ lãrin ọwọ́-ẹran ti o sanra, ati eyiti o rù.

21. Nitoriti ẹnyin ti fi ẹgbẹ́ ati ejiká gbún, ti ẹ si ti fi iwo nyin kàn gbogbo awọn ti o li àrun titi ẹ fi tú wọn kakiri.

22. Nitorina ni emi o ṣe gbà ọwọ́-ẹran mi là, nwọn kì yio si jẹ ijẹ́ mọ, emi o si ṣe idajọ lãrin ẹran ati ẹran.

23. Emi o si gbe oluṣọ́ agutan kan soke lori wọn, on o si bọ́ wọn, ani Dafidi iranṣẹ mi; on o bọ́ wọn, on o si jẹ oluṣọ́ agutan wọn.

24. Emi Oluwa yio si jẹ Ọlọrun wọn, ati Dafidi iranṣẹ mi o jẹ ọmọ-alade li ãrin wọn, emi Oluwa li o ti sọ ọ.

25. Emi o si ba wọn da majẹmu alafia, emi o si jẹ ki awọn ẹranko buburu dasẹ ni ilẹ na: nwọn o si ma gbe aginju li ailewu, nwọn o si sùn ninu igbó.

26. Emi o si ṣe awọn ati ibi ti o yi oke mi ká ni ibukún; emi o si jẹ ki ojò ki o rọ̀ li akoko rẹ̀, òjo ibukún yio wà.

27. Igi igbẹ́ yio si so eso rẹ̀, ilẹ yio si ma mu asunkun rẹ̀ wá, nwọn o si wà li alafia ni ilẹ wọn, nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati emi o ti ṣẹ́ èdídi àjaga wọn, ti emi o si ti gbà wọn lọwọ awọn ti nwọn nsìn bi ẹrú.

28. Nwọn kì yio si ṣe ijẹ fun awọn keferi mọ, bẹ̃ni ẹranko ilẹ na kì yio pa wọn jẹ, ṣugbọn nwọn o wà li alafia ẹnikẹni kì yio si dẹrùba wọn,

29. Emi o si gbe igi okiki kan soke fun wọn, ebi kì yio si run wọn ni ilẹ na mọ, bẹ̃ni nwọn kì yio rù itiju awọn keferi mọ.

30. Bayi ni nwọn o mọ̀ pe emi Oluwa Ọlọrun wọn wà pẹlu wọn, ati awọn, ile Israeli, jẹ enia mi, li Oluwa Ọlọrun wi.

Ka pipe ipin Esek 34