Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 33:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe,

2. Ọmọ enia, sọ fun awọn ọmọ enia rẹ, si wi fun wọn pe, Bi emi bá mu idà wá sori ilẹ kan, bi awọn enia ilẹ na bá mu ọkunrin kan ninu ara wọn, ti nwọn si fi ṣe oluṣọ́ wọn:

3. Bi on bá ri ti idà mbọ̀ wá sori ilẹ na ti o bá fun ipè, ti o si kìlọ fun awọn enia na:

4. Nigbana ẹnikẹni ti o bá gbọ́ iró ipè, ti kò si gbà ìkilọ; bi idà ba de, ti o si mu on kuro, ẹjẹ rẹ̀ yio wà lori on tikalarẹ̀.

5. O gbọ́ iró ipè, kò si gbà ìkilọ: ẹ̀jẹ rẹ̀ yio wà lori rẹ̀. Ṣugbọn ẹniti o gbọ́ ìkilọ yio gbà ọkàn ara rẹ̀ là.

6. Ṣugbọn bi oluṣọ́ na bá ri ti idà mbọ̀, ti kò si fun ipè, ti a kò si kìlọ fun awọn enia; bi idà ba de, ti o ba si mu ẹnikẹni lãrin wọn, a mu u kuro nitori aiṣedẽde rẹ̀, ṣugbọn ẹjẹ rẹ̀ li emi o bere lọwọ oluṣọ́ na.

7. Bẹ̃ni, iwọ ọmọ enia, emi ti fi ọ ṣe oluṣọ́ fun ile Israeli; nitorina iwọ o gbọ́ ọ̀rọ li ẹnu mi, iwọ o si kìlọ fun wọn lati ọdọ mi.

8. Nigbati emi ba wi fun enia buburu pe, Iwọ enia buburu, kikú ni iwọ o kú, bi iwọ kò bá sọ̀rọ lati kìlọ fun enia buburu na ki o kuro li ọ̀na rẹ̀, enia buburu na yio kú nitori aiṣedẽde rẹ̀, ṣugbọn ẹjẹ rẹ̀ li emi o bere li ọwọ́ rẹ.

Ka pipe ipin Esek 33