Nigbati emi ba wi fun enia buburu pe, Iwọ enia buburu, kikú ni iwọ o kú, bi iwọ kò bá sọ̀rọ lati kìlọ fun enia buburu na ki o kuro li ọ̀na rẹ̀, enia buburu na yio kú nitori aiṣedẽde rẹ̀, ṣugbọn ẹjẹ rẹ̀ li emi o bere li ọwọ́ rẹ.