Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 32:19-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Tani iwọ julọ li ẹwà? sọkalẹ, ki a si tẹ́ ọ tì awọn alaikọla.

20. Nwọn o ṣubu li ãrin awọn ti a fi idà pa: a fi on le idà lọwọ: fà a, ati awọn ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀.

21. Awọn alagbara lãrin awọn alagbara yio sọ̀rọ si i lati ãrin ipò-okú wá, pẹlu awọn ti o ràn a lọwọ: nwọn sọkalẹ lọ, nwọn dubulẹ, awọn alaikọla ti a fi idà pa.

22. Assuru wà nibẹ̀ ati gbogbo ẹgbẹ́ rẹ̀: awọn ibojì rẹ̀ wà lọdọ rẹ̀: gbogbo wọn li a pa, ti o ti ipa idà ṣubu:

23. Ibojì awọn ẹniti a gbe kà ẹgbẹ́ ihò, awọn ẹgbẹ́ rẹ̀ si yi ibojì rẹ̀ ka, gbogbo wọn li a pa, nwọn ti ipa idà ṣubu, ti o da ẹ̀ru silẹ ni ilẹ alãye.

24. Elamu wà nibẹ, ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀ yi ibojì rẹ̀ ka, gbogbo wọn li a pa, nwọn ti ipa idà ṣubu, ti nwọn sọkalẹ li alaikọla si ìsalẹ aiye, ti o da ẹ̀ru wọn silẹ ni ilẹ alãye; sibẹ nwọn ti rù itiju wọn pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò.

25. Nwọn ti gbe akete kan kalẹ fun u li ãrin awọn ti a pa pẹlu gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀: awọn ibojì rẹ̀ yi i ka, gbogbo wọn alaikọla ti a fi idà pa: bi a tilẹ dá ẹ̀ru wọn silẹ ni ilẹ alãye, sibẹ nwọn ti rù itiju wọn pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò: a fi i si ãrin awọn ti a pa.

26. Meṣeki ati Tubali wà nibẹ, ati gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀: awọn ibojì rẹ̀ yi i ka: gbogbo wọn alaikọlà ti a fi idà pa, bi nwọn tilẹ dá ẹ̀ru wọn silẹ ni ilẹ alãye.

27. Nwọn kì yio si dubulẹ tì awọn alagbara ti o ṣubu ninu awọn alaikọlà, ti nwọn sọkalẹ lọ si ipò-okú pẹlu ihámọra ogun wọn: nwọn ti fi idà wọn rọ ori wọn, ṣugbọn aiṣedẽde wọn yio wà lori egungun wọn, bi nwọn tilẹ jẹ ẹ̀ru awọn alagbara ni ilẹ alãye.

28. Lõtọ, a o fọ́ ọ lãrin awọn alaikọlà, iwọ o si dubulẹ tì awọn ti a fi idà pa.

29. Edomu wà nibẹ, awọn ọba rẹ̀, ati awọn ọmọ-alade rẹ̀, ti a tẹ́ pẹlu agbara wọn tì awọn ti a fi idà pa, nwọn o dubulẹ tì awọn alaikọlà, ati pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò.

30. Awọn ọmọ-alade ariwa wà nibẹ, gbogbo wọn, ati awọn ara Sidoni, ti nwọn sọkalẹ lọ pẹlu awọn ti a pa; pẹlu ẹ̀ru wọn, oju agbara wọn tì wọn; nwọn si dubulẹ li alaikọlà pẹlu awọn ti a fi idà pa, nwọn si rù itiju wọn pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò.

31. Farao yio ri wọn, a o si tù u ninu lori gbogbo ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀, ani Farao ati gbogbo ogun rẹ̀ ti a fi idà pa, li Oluwa Ọlọrun wi.

Ka pipe ipin Esek 32