Awọn ọmọ-alade ariwa wà nibẹ, gbogbo wọn, ati awọn ara Sidoni, ti nwọn sọkalẹ lọ pẹlu awọn ti a pa; pẹlu ẹ̀ru wọn, oju agbara wọn tì wọn; nwọn si dubulẹ li alaikọlà pẹlu awọn ti a fi idà pa, nwọn si rù itiju wọn pẹlu awọn ti o sọkalẹ lọ si ihò.