Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 30:6-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Bayi li Oluwa wi; Awọn pẹlu ti nwọn gbe Egipti ró yio ṣubu; ati igberaga agbara rẹ̀ yio sọkalẹ: lati Migdoli lọ de Siene ni nwọn o ti ipà idà ṣubu ninu rẹ̀, li Oluwa Ọlọrun wi.

7. Nwọn o si di ahoro li ãrin awọn ilẹ ti o di ahoro, ilu rẹ̀ yio si wà li àrin awọn ilu ti o di ahoro.

8. Nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati mo bá gbe iná kalẹ ni Egipti, ti gbogbo awọn olùranlọ́wọ rẹ̀ bá parun.

9. Li ọjọ na ni onṣẹ yio lọ lati ọdọ mi ninu ọkọ̀, lati dẹ̀ruba Etiopia ti o wà li alafia, irora yio wá sori wọn gẹgẹ bi li ọjọ Egipti: kiyesi i, o de.

10. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi o si ṣe ki ọ̀pọlọpọ enia Egipti ki o ti ipa ọwọ́ Nebukaddressari ọba Babiloni dínkù.

11. On ati enia rẹ̀ pẹlu rẹ̀, ẹ̀ru awọn orilẹ-ède, li a o mu wá pa ilẹ na run: nwọn o si fà idà wọn yọ si Egipti, nwọn o si fi awọn ti a pa kún ilẹ na.

12. Emi o mu gbogbo odò wọn gbẹ, emi o si tà ilẹ na si ọwọ́ awọn enia buburu; emi o si ti ipa ọwọ́ awọn alejo sọ ilẹ wọn di ahoro, ati ẹkún rẹ̀: Emi Oluwa li o ti sọ ọ.

13. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; emi o pa awọn oriṣa run pẹlu, emi o si jẹ ki ere wọn tán ni Nofi; kì yio si si ọmọ alade kan ni ilẹ Egipti mọ́: emi o si fi ẹ̀ru si ilẹ Egipti.

14. Emi o si sọ Patrosi di ahoro, emi o si gbe iná kalẹ ni Soani, emi o si mu idajọ ṣẹ ni No.

15. Emi o si dà irúnu mi si ori Sini, agbara Egipti; emi o si ké ọ̀pọlọpọ enia No kuro.

16. Emi o si gbe iná kalẹ ni Egipti, Sini yio ni irora nla, a o si fà No ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, Nofi yio si ni ipọnju lojojumọ.

17. Awọn ọdọmọkunrin Afeni ati Pibeseti yio ti ipa idà ṣubu: ati awọn wọnyi yio lọ si igbèkun.

18. Ọjọ yio si ṣõkun ni Tehafnehesi, nigbati emi bá dá àjaga ọrùn Egipti nibẹ: ọṣọ́ agbara rẹ̀ yio tán ninu rẹ̀: bi o ṣe tirẹ̀ ni, ikũkũ yio bò on, ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin yio lọ si igbèkun.

Ka pipe ipin Esek 30