Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 29:18-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Ọmọ enia, Nebukadresari ọba Babiloni mu ki ogun rẹ̀ sìn irú nla si Tire: gbogbo ori pá, ati gbogbo èjiká bó: sibẹsibẹ on, ati awọn ogun rẹ̀, kò ri owo ọ̀ya gbà, lati Tire fun irú ti o ti sìn si i:

19. Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Kiyesi i, emi o fi ilẹ Egipti fun Nebukadresari ọba Babiloni; yio si kó awọn ọ̀pọlọpọ enia rẹ̀, ati ikógun rẹ̀, ati ijẹ rẹ̀; yio si jẹ owo ọ̀ya fun awọn ogun rẹ̀.

20. Mo ti fi ilẹ Egipti fun u, fun irú ti o sìn si i, nitoriti nwọn ṣiṣẹ́ fun mi, li Oluwa Ọlọrun wi.

21. Li ọjọ na li emi o mu ki iwọ Israeli rú jade, emi o si fun ọ ni iṣínu li ãrin wọn; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

Ka pipe ipin Esek 29