Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 28:16-26 Yorùbá Bibeli (YCE)

16. Nitori ọ̀pọlọpọ òwo rẹ, nwọn ti fi iwà-ipa kún ãrin rẹ, iwọ si ti ṣẹ̀: nitorina li emi o ṣe sọ ọ nù bi ohun ailọ̀wọ kuro li oke Ọlọrun: emi o si pa ọ run, iwọ kerubu ti o bò, kuro lãrin okuta iná.

17. Ọkàn rẹ gbe soke nitori ẹwà rẹ, o ti bà ọgbọ́n rẹ jẹ nitori dídan rẹ; emi o bì ọ lulẹ, emi o gbe ọ kalẹ niwaju awọn ọba, ki nwọn ba le wò ọ.

18. Iwọ ti bà ibi mimọ́ rẹ jẹ nipa ọ̀pọlọpọ aiṣedẽde rẹ, nipa aiṣedẽde òwo rẹ; nitorina emi o mu iná jade lati ãrin rẹ wá, yio jó ọ run, emi o si sọ ọ di ẽru lori ilẹ loju gbogbo awọn ti o wò ọ:

19. Gbogbo awọn ti o mọ̀ ọ lãrin awọn orilẹ-ède li ẹnu o yà si ọ: iwọ o jẹ ẹ̀ru, iwọ kì yio si si mọ́ lailai.

20. Ọ̀rọ Oluwa tun tọ̀ mi wá, wipe,

21. Ọmọ enia, gbé oju rẹ si Sidoni, ki o si sọtẹlẹ si i,

22. Si wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; Sa wò o, Emi doju kọ ọ, iwọ Sidoni; a o si ṣe mi logo li ãrin rẹ, nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa, nigbati emi o bá ti mu idajọ mi ṣẹ ninu rẹ̀, ti a o si yà mi si mimọ́ ninu rẹ̀.

23. Emi o si rán àjakálẹ àrun sinu rẹ̀, ati ẹjẹ ni igboro rẹ̀; a o si fi idà pa awọn si a ṣá li ọgbẹ li ãrin rẹ̀ lori rẹ̀ nihà gbogbo; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

24. Kì yio si si ẹgún ti ngún ni fun ile Israeli mọ́, tabi ẹgún bibani ninu jẹ́ ti gbogbo awọn ti o yi wọn ká, ti o si ṣãtá wọn; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa Ọlọrun.

25. Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Nigbati emi o bá ti kó ile Israeli jọ kuro lãrin awọn orilẹ-ède ti a tú wọn ká si, ti a o si yà mi si mimọ́ ninu wọn loju awọn keferi, nigbana ni nwọn o gbé ilẹ wọn ti mo ti fi fun Jakobu iranṣẹ mi.

26. Nwọn o si ma gbé inu rẹ̀ ni ibalẹ-aiya, nwọn o si kọ́ ile, nwọn o si gbìn ọgbà àjara; nitõtọ, nwọn o wà ni ibalẹ-aiya, nigbati emi bá ti mu idajọ mi ṣẹ si ara awọn ti ngàn wọn yi wọn kakiri, nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa Ọlọrun wọn.

Ka pipe ipin Esek 28