Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 24:20-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Mo si da wọn lohùn pe, Ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá wipe,

21. Sọ fun ile Israeli pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, kiyesi i emi o sọ ibi mimọ́ mi di aimọ́, titayọ agbara nyin, ifẹ oju nyin, ikãnu ọkàn nyin, ati ọmọ nyin ọkunrin ati ọmọ nyin obinrin, ti ẹnyin ti fi silẹ, yio ti ipa idà ṣubu.

22. Ẹnyin o si ṣe bi emi ti ṣe: ẹnyin kò ni bò ète nyin, bẹ̃ni ẹ kò ni jẹ onjẹ enia.

23. Lawani nyin yio si wà li ori nyin, ati bàta nyin li ẹsẹ nyin: ẹnyin kò ni gbãwẹ, bẹ̃ni ẹ kò ni sọkun: ṣugbọn ẹnyin o ma joro nitori aiṣedẽde nyin, ẹ o si ma ṣọ̀fọ ẹnikan si ẹnikeji.

24. Bayi ni Esekieli jẹ àmi fun nyin: gẹgẹ bi gbogbo ohun ti o ṣe, li ẹ o si ṣe nigbati eyi bá si de, ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa Ọlọrun:

25. Pẹlupẹlu, iwọ ọmọ enia, kì yio ha ṣe pe, ni ijọ na nigbati mo ba gbà agbara wọn, ayọ̀ ogo wọn, ifẹ oju wọn, ati eyiti nwọn gbe ọkàn wọn le, ọmọ wọn ọkunrin, ati ọmọ wọn obinrin, kuro lọdọ wọn,

26. Ti ẹniti ti o ba sálà nijọ na, yio tọ̀ ọ wá, lati jẹ ki iwọ ki o fi eti ara rẹ gbọ́?

27. Li ọjọ na li ẹnu rẹ yio ṣi si ẹni ti o sala, iwọ o si sọ̀rọ, iwọ kì yio si yadi mọ: iwọ o si jẹ àmi fun wọn; nwọn o si mọ̀ pe emi li Oluwa.

Ka pipe ipin Esek 24