Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 24:15-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

15. Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá, wipe,

16. Ọmọ enia, kiye si i, mo mu ifẹ oju rẹ kuro lọdọ rẹ, nipa lilù kan: ṣugbọn iwọ kò gbọdọ gbãwẹ, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sọkun, bẹ̃ni omije rẹ kò gbọdọ ṣan silẹ.

17. Máṣe sọkun, máṣe gbãwẹ fun okú, wé lawàni sori rẹ, si bọ̀ bata rẹ si ẹsẹ rẹ, máṣe bò ète rẹ, máṣe jẹ onjẹ enia.

18. Bẹ̃ni mo sọ fun awọn enia li owurọ: li aṣálẹ obinrin mi si kú, mo si ṣe li owurọ bi a ti pá a li aṣẹ fun mi.

19. Awọn enia si sọ fun mi wipe, Iwọ kì yio ha sọ fun wa ohun ti nkan wọnyi jasi fun wa, ti iwọ ṣe bayi?

20. Mo si da wọn lohùn pe, Ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá wipe,

21. Sọ fun ile Israeli pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, kiyesi i emi o sọ ibi mimọ́ mi di aimọ́, titayọ agbara nyin, ifẹ oju nyin, ikãnu ọkàn nyin, ati ọmọ nyin ọkunrin ati ọmọ nyin obinrin, ti ẹnyin ti fi silẹ, yio ti ipa idà ṣubu.

22. Ẹnyin o si ṣe bi emi ti ṣe: ẹnyin kò ni bò ète nyin, bẹ̃ni ẹ kò ni jẹ onjẹ enia.

23. Lawani nyin yio si wà li ori nyin, ati bàta nyin li ẹsẹ nyin: ẹnyin kò ni gbãwẹ, bẹ̃ni ẹ kò ni sọkun: ṣugbọn ẹnyin o ma joro nitori aiṣedẽde nyin, ẹ o si ma ṣọ̀fọ ẹnikan si ẹnikeji.

24. Bayi ni Esekieli jẹ àmi fun nyin: gẹgẹ bi gbogbo ohun ti o ṣe, li ẹ o si ṣe nigbati eyi bá si de, ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa Ọlọrun:

Ka pipe ipin Esek 24