Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 20:4-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

4. Iwọ o ha dá wọn lẹjọ bi, ọmọ enia, iwọ o ha da wọn lẹjọ? jẹ ki wọn mọ̀ ohun-irira baba wọn.

5. Si wi fun wọn pe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Ni ọjọ na nigbati mo yàn Israeli, ti mo si gbe ọwọ́ mi soke si iru-ọmọ ile Jakobu, ti mo si sọ ara mi di mimọ̀ fun wọn ni ilẹ Egipti, nigbati mo gbe ọwọ́ mi soke si wọn, wipe, Emi ni Oluwa Ọlọrun nyin:

6. Ni ọjọ ti mo gbe ọwọ́ mi soke si wọn, lati mu wọn jade lati ilẹ Egipti si ilẹ ti mo ti wò silẹ fun wọn, ti nṣàn fun wàra ati fun oyin, ti iṣe ogo gbogbo ilẹ.

7. Mo si wi fun wọn pe, Ki olukuluku ninu nyin gbe irira oju rẹ̀ junù, ẹ má si ṣe fi oriṣa Egipti sọ ara nyin di aimọ́: emi ni Oluwa Ọlọrun nyin.

8. Ṣugbọn nwọn ṣọ̀tẹ si mi, nwọn kò si fẹ fi eti si mi: olukuluku wọn kò gbe ohun-irira oju wọn junù, bẹ̃ni nwọn kò kọ oriṣa Egipti silẹ: nigbana ni mo wipe, emi o da irúnu mi si wọn lori, lati pari ibinu mi si wọn lãrin ilẹ Egipti.

9. Ṣugbọn mo ṣiṣẹ nitori orukọ mi; ki o má bà bajẹ niwaju awọn keferi, lãrin ẹniti nwọn wà, loju ẹniti mo sọ ara mi di mimọ̀ fun wọn, ni mimu wọn jade kuro ni ilẹ Egipti.

10. Mo si jẹ ki wọn lọ kuro ni ilẹ Egipti, mo si mu wọn wá si aginju.

11. Mo si fi aṣẹ mi fun wọn, mo si fi idajọ mi hàn wọn, eyiti bi enia kan ba ṣe, yio tilẹ yè ninu wọn.

12. Pẹlupẹlu mo si fun wọn ni ọjọ isimi mi, lati ṣe àmi lãrin t'emi ti wọn, ki nwọn ki o le mọ̀ pe emi ni Oluwa ti o yà wọn si mimọ́.

13. Ṣugbọn ile Israeli ṣọ̀tẹ si mi ni aginjù: nwọn kò rìn ni aṣẹ mi, nwọn si gàn idajọ mi, eyiti bi enia kan ba ṣe, on o tilẹ yè ninu wọn; ati ọjọ isimi mi ni wọn tilẹ bajẹ gidigidi: nigbana ni mo wipe, emi o dà irúnu mi si wọn lori li aginju, lati pa wọn run.

Ka pipe ipin Esek 20