Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 17:13-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. O si ti mu ninu iru-ọmọ ọba, o si bá a dá majẹmu, o si ti mu u bura: o si mu awọn alagbara ilẹ na pẹlu:

14. Ki ijọba na le jẹ alailọla, ki o má le gbe ara rẹ̀ soke, ki o le duro nipa pipa majẹmu rẹ̀ mọ.

15. Ṣugbọn on ṣọ̀tẹ si i ni rirán awọn ikọ̀ rẹ̀ lọ si Egipti, ki nwọn ki o le fi ẹṣin fun u ati enia pupọ. Yio ha sàn a? ẹniti nṣe iru nkan wọnyi yio ha bọ́? tabi yio dalẹ tan ki o si bọ́?

16. Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, nitotọ ibi ti ọba ngbe ti o fi i jọba, ibura ẹniti o gàn, majẹmu ẹniti o si bajẹ, ani lọdọ rẹ̀ lãrin Babiloni ni yio kú.

17. Bẹ̃ni Farao ti on ti ogun rẹ̀ ti o li agbara ati ẹgbẹ́ nla kì yio ṣe fun u ninu ogun, nipa mimọ odi, ati kikọle iṣọ́ ti o li agbara, lati ke enia pupọ̀ kuro:

18. Nitoriti o gàn ibura nipa didalẹ, kiye si i, o ti fi ọwọ́ rẹ̀ fun ni, o si ti ṣe gbogbo nkan wọnyi, kì yio bọ́.

19. Nitorina bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Bi mo ti wà, dajudaju ibura mi ti o ti gàn, ati majẹmu mi ti o ti dà, ani on li emi o san si ori on tikalarẹ̀.

20. Emi o si nà àwọn mi si i lori, a o si mu u ninu ẹgẹ́ mi; emi o si mu u de Babiloni, emi o si ba a rojọ nibẹ, nitori ẹ̀ṣẹ ti o ti da si mi.

21. Ati gbogbo awọn isánsa rẹ̀ pẹlu gbogbo awọn ẹgbẹ́-ogun rẹ̀, ni yio ti oju idà ṣubu; awọn ti o si kù ni a o tuka si gbogbo ẹfũfu: ẹnyin o si mọ̀ pe emi Oluwa li o ti sọ ọ.

22. Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; emi o mu ninu ẹka ti o ga jùlọ, ninu igi Kedari giga; emi o si lọ́ ọ, emi o ke ọ̀munú ẹka kan kuro ninu ọ̀munú ẹka rẹ̀; emi o si gbìn i sori oke giga kan ti o si hàn:

23. Lori oke giga ti Israeli ni emi o gbìn i si, yio si yọ ẹka; yio si so eso, yio si jẹ igi Kedari daradara; labẹ rẹ̀ ni gbogbo ẹiyẹ oniruru iyẹ́ o si gbe; ninu ojiji ẹka rẹ̀ ni nwọn o gbe.

24. Gbogbo igi inu igbẹ ni yio si mọ̀ pe, emi Oluwa li o ti mu igi giga walẹ, ti mo ti gbe igi rirẹlẹ soke, ti mo ti mu igi tutù gbẹ, ti mo si ti mu igi gbigbẹ ruwé: emi Oluwa li o ti sọ ti mo si ti ṣe e.

Ka pipe ipin Esek 17