Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 16:49-61 Yorùbá Bibeli (YCE)

49. Kiyesi i, ẹ̀ṣẹ Sodomu arabinrin rẹ niyi, irera, onjẹ ajẹyo, ati ọ̀pọlọpọ orayè wà ninu rẹ̀, ati ninu awọn ọmọ rẹ̀ obinrin; bẹ̃ni on kò mu ọwọ́ talaka ati alaini lokun.

50. Nwọn si gberaga, nwọn si ṣe ohun irira niwaju mi: nitorina ni mo mu wọn kuro gẹgẹ bi mo ti ri pe o dara.

51. Bẹ̃ni Samaria kò dá abọ̀ ẹ̀ṣẹ rẹ: ṣugbọn iwọ sọ ohun irira rẹ di pupọ jù wọn lọ, o si ti da awọn arabinrin rẹ lare ninu gbogbo ohun irira rẹ ti iwọ ti ṣe.

52. Iwọ pẹlu, ti o ti da awọn arabinrin rẹ lẹbi, ru itiju ara rẹ, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ ti iwọ ti ṣe ni iṣe irira jù wọn lọ: awọn ṣe olododo jù iwọ lọ; nitotọ, ki iwọ ki o dãmu pẹlu, si ru itiju rẹ, nitipe iwọ dá awọn arabinrin rẹ lare.

53. Nigbati mo ba tun mu igbèkun wọn wá, igbèkun Sodomu ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, pẹlu igbèkun Samaria ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, nigbana li emi o tun mu igbèkun awọn onde rẹ wá lãrin wọn:

54. Ki iwọ ki o le ru itiju ara rẹ, ki o si le dãmu ni gbogbo eyi ti o ti ṣe, nitipe iwọ jẹ itunu fun wọn.

55. Nigbati awọn arabinrin rẹ Sodomu, ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, ba pada si ipò wọn iṣaju, ti Samaria ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin ba pada si ipò wọn iṣaju, nigbana ni iwọ ati awọn ọmọ rẹ obinrin yio pada si ipò nyin iṣaju.

56. Nitori ẹnu rẹ kò da orukọ Sodomu arabinrin rẹ li ọjọ irera rẹ,

57. Ki a to ri ìwa buburu rẹ, bi akoko ti awọn ọmọbinrin Siria gàn ọ, ati gbogbo awọn ti o wà yi i ka, awọn ọmọbinrin Filistia ti o gàn ọ ka kiri.

58. Iwọ ti ru ifẹkufẹ rẹ ati ohun irira rẹ, ni Oluwa wi.

59. Nitori bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Emi o tilẹ ba ọ lò gẹgẹ bi iwọ ti ṣe, ti iwọ ti gàn ibura nipa biba majẹmu jẹ.

60. Ṣugbọn emi o ranti majẹmu mi pẹlu rẹ, ni ọjọ ewe rẹ, emi o si gbe majẹmu aiyeraiye kalẹ fun ọ.

61. Iwọ o si ranti ọ̀na rẹ, oju o si tì ọ, nigbati iwọ ba gba awọn arabinrin rẹ, ẹgbọ́n rẹ ati aburò rẹ: emi o si fi wọn fun ọ bi ọmọbinrin, ṣugbọn ki iṣe nipa majẹmu rẹ.

Ka pipe ipin Esek 16