Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 16:47-54 Yorùbá Bibeli (YCE)

47. Ṣugbọn iwọ kò rin ni ọ̀na wọn, iwọ kò si ṣe gẹgẹ bi irira wọn: ṣugbọn, bi ẹnipe ohun kekere ni eyini, iwọ bajẹ jù wọn lọ ni gbogbo ọ̀na rẹ.

48. Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, Sodomu arabinrin rẹ, on, tabi awọn ọmọ rẹ̀ obinrin kò ṣe gẹgẹ bi iwọ ti ṣe, iwọ ati awọn ọmọ rẹ obinrin.

49. Kiyesi i, ẹ̀ṣẹ Sodomu arabinrin rẹ niyi, irera, onjẹ ajẹyo, ati ọ̀pọlọpọ orayè wà ninu rẹ̀, ati ninu awọn ọmọ rẹ̀ obinrin; bẹ̃ni on kò mu ọwọ́ talaka ati alaini lokun.

50. Nwọn si gberaga, nwọn si ṣe ohun irira niwaju mi: nitorina ni mo mu wọn kuro gẹgẹ bi mo ti ri pe o dara.

51. Bẹ̃ni Samaria kò dá abọ̀ ẹ̀ṣẹ rẹ: ṣugbọn iwọ sọ ohun irira rẹ di pupọ jù wọn lọ, o si ti da awọn arabinrin rẹ lare ninu gbogbo ohun irira rẹ ti iwọ ti ṣe.

52. Iwọ pẹlu, ti o ti da awọn arabinrin rẹ lẹbi, ru itiju ara rẹ, nitori ẹ̀ṣẹ rẹ ti iwọ ti ṣe ni iṣe irira jù wọn lọ: awọn ṣe olododo jù iwọ lọ; nitotọ, ki iwọ ki o dãmu pẹlu, si ru itiju rẹ, nitipe iwọ dá awọn arabinrin rẹ lare.

53. Nigbati mo ba tun mu igbèkun wọn wá, igbèkun Sodomu ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, pẹlu igbèkun Samaria ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin, nigbana li emi o tun mu igbèkun awọn onde rẹ wá lãrin wọn:

54. Ki iwọ ki o le ru itiju ara rẹ, ki o si le dãmu ni gbogbo eyi ti o ti ṣe, nitipe iwọ jẹ itunu fun wọn.

Ka pipe ipin Esek 16