Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 11:2-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. O si wi fun mi pe, Ọmọ enia, awọn ọkunrin ti npete ikà ni wọnyi, ti nsi gbimọ̀ buburu ni ilu yi:

3. Awọn ti o wipe, Kò sunmọ tosi; ẹ jẹ ki a kọ ile: ilu yi ni ìgba, awa si ni ẹran.

4. Nitorina sọtẹlẹ si wọn, Ọmọ enia, sọtẹlẹ.

5. Ẹmi Oluwa si bà le mi, o si wi fun mi pe, Sọ̀rọ; Bayi li Oluwa wi; Bayi li ẹnyin ti wi, Ile Israeli, nitoriti mo mọ̀ olukuluku ohun ti o wá si inu nyin.

6. Ẹnyin ti sọ okú nyin di pupọ̀ ni ilu yi, ẹnyin si ti fi okú kún igboro rẹ̀,

7. Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Awọn okú nyin ti ẹnyin ti tẹ́ si ãrin rẹ̀, awọn ni ẹran, ilu yi si ni ìgba; ṣugbọn emi o mu nyin jade kuro lãrin rẹ̀.

8. Oluwa Ọlọrun wipe, Ẹnyin ti bẹ̀ru idà, emi o si mu idà wa sori nyin.

Ka pipe ipin Esek 11