Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 10:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. MO si wò, si kiye si i, ninu ofurufu ti o wà loke lori awọn kerubu, ohun kan hàn li ori wọn bi okuta safire bi irí aworan itẹ́.

2. O si sọ fun ọkunrin ti o wọ aṣọ ọ̀gbọ, o si wipe, Bọ sarin kẹkẹ, labẹ kerubu; si bu ikúnwọ ẹyin iná lati agbedemeji awọn kerubu; si fọ́n wọn ka sori ilu na. O si wọ inu ile li oju mi.

3. Awọn kerubu si duro li apá ọtun ile na, nigbati ọkunrin na wọ ile; awọ sanma si kún agbala ti inu.

4. Ogo Oluwa si goke lọ kuro lori kerubu o si duro loke iloro ile na; ile na si kún fun awọsanma, agbala na si kùn fun didán ogo Oluwa.

5. A si gbọ́ iró iyẹ awọn kerubu titi de agbala ode, bi ohùn Ọlọrun Oludumare nigbati o nsọ̀rọ.

6. O si ṣe, nigbati o ti paṣẹ fun ọkunrin ti o wọ aṣọ ọgbọ, wipe, Fọn iná lati ãrin awọn kẹkẹ, lati ãrin awọn kerubu, o si wọ inu ile, o si duro lẹba awọn kẹkẹ.

7. Kerubu kan si nà ọwọ́ rẹ̀ jade lati ãrin awọn kerubu si iná ti o wà li ãrin awọn kerubu, o si mu ninu rẹ̀, o si fi si ọwọ́ ẹniti o wọ aṣọ ọgbọ̀: ẹniti o gbà a; ti o si jade lọ.

8. Aworan ọwọ́ enia si hàn ninu awọn kerubu labẹ iyẹ́ wọn.

9. Nigbati mo si wò, kiye si i, awọn kẹkẹ mẹrin na niha awọn kerubu, kẹkẹ kan niha kerubu kan, ati kẹkẹ miran niha kerubu miran; irí awọn kẹkẹ na si dabi awọ̀ okuta berili.

Ka pipe ipin Esek 10