Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Esek 10:1-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. MO si wò, si kiye si i, ninu ofurufu ti o wà loke lori awọn kerubu, ohun kan hàn li ori wọn bi okuta safire bi irí aworan itẹ́.

2. O si sọ fun ọkunrin ti o wọ aṣọ ọ̀gbọ, o si wipe, Bọ sarin kẹkẹ, labẹ kerubu; si bu ikúnwọ ẹyin iná lati agbedemeji awọn kerubu; si fọ́n wọn ka sori ilu na. O si wọ inu ile li oju mi.

3. Awọn kerubu si duro li apá ọtun ile na, nigbati ọkunrin na wọ ile; awọ sanma si kún agbala ti inu.

4. Ogo Oluwa si goke lọ kuro lori kerubu o si duro loke iloro ile na; ile na si kún fun awọsanma, agbala na si kùn fun didán ogo Oluwa.

5. A si gbọ́ iró iyẹ awọn kerubu titi de agbala ode, bi ohùn Ọlọrun Oludumare nigbati o nsọ̀rọ.

6. O si ṣe, nigbati o ti paṣẹ fun ọkunrin ti o wọ aṣọ ọgbọ, wipe, Fọn iná lati ãrin awọn kẹkẹ, lati ãrin awọn kerubu, o si wọ inu ile, o si duro lẹba awọn kẹkẹ.

7. Kerubu kan si nà ọwọ́ rẹ̀ jade lati ãrin awọn kerubu si iná ti o wà li ãrin awọn kerubu, o si mu ninu rẹ̀, o si fi si ọwọ́ ẹniti o wọ aṣọ ọgbọ̀: ẹniti o gbà a; ti o si jade lọ.

8. Aworan ọwọ́ enia si hàn ninu awọn kerubu labẹ iyẹ́ wọn.

Ka pipe ipin Esek 10