Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 34:24-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Nitoriti emi o lé awọn orilẹ-ède nì jade niwaju rẹ, emi o si fẹ̀ ipinlẹ rẹ: bẹ̃li ẹnikẹni ki yio fẹ́ ilẹ̀-iní rẹ, nigbati iwọ o gòke lọ lati pejọ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ li ẹrinmẹta li ọdún kan.

25. Iwọ kò gbọdọ ta ẹ̀jẹ ẹbọ mi silẹ nibiti iwukàra wà, bẹ̃li ẹbọ ajọ irekọja kò gbọdọ kù titi di owurọ̀.

26. Akọ́so eso ilẹ rẹ ni ki iwọ ki o mú wa si ile OLUWA Ọlọrun rẹ. Iwọ kò gbọdọ bọ̀ ọmọ ewurẹ ninu warà iya rẹ̀.

27. OLUWA si wi fun Mose pe, Iwọ kọwe ọ̀rọ wọnyi: nitori nipa ìmọ ọ̀rọ wọnyi li emi bá iwọ ati Israeli dá majẹmu.

28. On si wà nibẹ̀, lọdọ OLUWA li ogoji ọsán ati ogoji oru: on kò jẹ onjẹ, bẹ̃ni kò mu omi. On si kọwe ọ̀rọ majẹmu na, ofin mẹwa nì, sara walã wọnni.

29. O si ṣe, nigbati Mose sọkalẹ lati ori òke Sinai wá ti on ti walã ẹrí mejeji nì li ọwọ́ Mose, nigbati o sọkalẹ ti ori òke na wá, ti Mose kò mọ̀ pe awọ oju on ndán nitoriti o bá a sọ̀rọ.

30. Nigbati Aaroni ati gbogbo awọn ọmọ Israeli ri Mose, kiyesi i, awọ oju rẹ̀ ndán; nwọn si bẹ̀ru lati sunmọ ọdọ rẹ̀.

31. Mose si kọ si wọn; ati Aaroni ati gbogbo awọn ijoye inu ajọ si pada tọ̀ ọ́ wá: Mose si bá wọn sọ̀rọ.

32. Lẹhin eyinì ni gbogbo awọn ọmọ Israeli si sunmọ ọ: o si paṣẹ gbogbo ohun ti OLUWA bá a sọ lori òke Sinai fun wọn.

33. Nigbati Mose si bá wọn sọ̀rọ tán, o fi iboju bò oju rẹ̀.

Ka pipe ipin Eks 34