12. OLUWA si wi fun Mose pe, Gòke tọ̀ mi wá sori òke, ki o si duro nibẹ̀; emi o si fi walã okuta fun ọ, ati aṣẹ kan, ati ofin ti mo ti kọ, ki iwọ ki o le ma kọ́ wọn.
13. Mose si dide, ati Joṣua iranṣẹ rẹ̀: Mose si gòke lọ si oke Ọlọrun.
14. O si wi fun awọn àgba na pe, Ẹ duro dè wa nihinyi, titi awa o fi tun pada tọ̀ nyin wá: si kiyesi i, Aaroni ati Huri mbẹ pẹlu nyin: bi ẹnikan ba li ọ̀ran kan, ki o tọ̀ wọn wá.
15. Mose si gòke lọ sori òke na, awọsanma si bò òke na mọlẹ.
16. Ogo OLUWA si sọkalẹ sori òke Sinai, awọsanma na si bò o mọlẹ ni ijọ́ mẹfa: ni ijọ́ keje o ké si Mose lati ãrin awọsanma wá.
17. Iwò ogo OLUWA dabi iná ajonirun li ori òke na li oju awọn ọmọ Israeli.
18. Mose si lọ sãrin awọsanma na, o sì gùn ori òke na: Mose si wà lori òke li ogoji ọsán ati ogoji oru.